Yíyọ Dino Melaye: INEC dá áwọn òṣìṣẹ́ lẹ́kọ̀ọ́

Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @dino_melaye

Àkọlé àwòrán, Dino Melaye ti ní àwọn òkú náà wà lára àwọn to kọ̀wé ẹ̀hónú nípa òun

Àjọ INEC ti parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí yóò kópa nínú ètò àti pe Sẹ́nétọ̀ tó ń ṣojú ẹkún ìdìbò ìwọ̀ oòrùn Kogi, Dino Melaye, pada wá sílé.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, alákòóso àjọ INEC ní ìpínlè Kogi, Ọ̀jọ̀gbọ́n James Apam, rọ àwọn òṣìṣẹ́ tó kópa láti mú iṣé náà lọ́kúnkúndún.

Awọn oṣisẹ INEC joko nibi idanilẹkọ wọn

Oríṣun àwòrán, INEC

Àkọlé àwòrán, Onírúurú ìjà àti awuyewuye ló ń wọ́ tọ orúkọ Dino Melaye

Ní ọdún tó kọjá, ni àwọn èèyàn kan lẹ́kùn ìdìbò ìwọ̀ oòrùn Kogi kọ̀wé ẹ̀hónú ṣọwọ́ sí àjọ INEC pé, àwọn fẹ́ kí Dino Melaye fi ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà sílẹ̀ máa bọ̀ nílé, nítorí àwọn kò fẹ́ẹ mọ́ gẹ́gẹ́ bi aṣojú àwọn.

Onírúurú ìjà àti awuyewuye ló ń wọ́ tọ orúkọ Dino Melaye lẹ́yìn lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.

Sẹ́nétọ̀ Dino Melaye ti ní, àwọn òkú náà wà lára àwọn to kọ̀wé ẹ̀hónú nípa òun.

Ó ni àwọn èèyàn kan ló ń ti òṣèlù bọ ọ̀rọ̀ náà.

Láìpé yìí ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kéde rẹ̀ pé wọ́n ń wáa lóríi ẹ̀sún ìpànìyàn ní ìpínlè Kogi.