Bàbáńgídá: Àwọn ọmọ Nàíjíríà kò kà mìí kún mọ́

Olórí ìjọba ológun tẹ́lẹ̀, Ajagunfẹ̀yìntì Ibrahim Badamọsi Babangida

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Kò sí ẹnití ó yìn mìí láwo pé mo sètò ìdìbò tó pegedé jùlọ nínú ìtàn orílẹ̀èdè yìí.

Olórí ìjọba ológun tẹ́lẹ̀, ajagunfẹ̀yìntì Ibrahim Babangida ti gbarata pé àwọn ọmọ Nàíjíríà ko ka òun sí mọ́ nítorí bí òun se wọ́gilé ìdìbò ààrẹ June 12.

Idìbò Aàrẹ June 12 ìdìbò kan gbógì tí gbogbo àgbáyé gbà pé òun ló péye jùlọ ninu itan orilẹẹde Nàíjíríà.

Babangida kéde bẹ́ẹ̀ lórí ètò orí móhùnmáwòràn án kan lọ́jọ́ ajé.

Bákan náà ló fikún un pé bí òun bá kọ̀wé nípa ìgbé ayé òun, kò sí ọmọ Nàíjíríà kankan tí yóò fẹ́ kàá.

Àkọlé fídíò, Ọdalẹ ni Babangida ati Abacha - Ọmọ Abiola

Wọn gbàgbé pé ọ̀rẹ́ ni èmi àti Abíọ́lá

"Lọ́ọ̀tọ́ ni mo wọ́gilé ìdìbò ààrẹ June 12, tí gbogbo àgbáyé gbà pé òun ló péye jùlọ, sùgbọ́n kò sí ẹnití ó yìn mìí láwo pé mo sètò ìdìbò tó pegedé jùlọ nínú ìtàn orílẹ̀èdè yìí."

Babangida tún fikun un pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ pé ọ̀rẹ́ ni òun àti Olóyè MKO Abiọ́lá ká tó di ìbò June 12 àti lẹ́yìn rẹ̀, tí kò sì sẹ́ni tó ròó pé sebí ọ̀rẹ́ làwọn méjèèjì, kín ló wá fa wàhálà yìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: