Barbara Bush: Aya ààrẹ Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Getty AFP
Ìyàwó ààrẹ orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀, Barbara Bush ti kú ní ẹni ọdún méjìléláàádọ̀rún .
Nígbà ayé rẹ̀, arábìnrin Barbara Bush ni ìyálé àgbà ní agbolé Bush, níbi tí ààrẹ orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti jáde wá.
Ọkọ rẹ̀, George Bush àgbà pẹlú ọmọ rẹ̀, George W Bush kékeré.
Láàárín ọdún 1989 sí 1993, ló fi dipò ìyàwó ààrẹ mú, ó sì ti ṣe díẹ ̀ tí ó ti wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, tí kò sì gbà kí wọ́n tọ́jú òun.

Oríṣun àwòrán, BBC TV
Ọmọ rẹ̀, George W Bush sọọ́ nínú àtẹ̀jáde kan pé: " Ìyá mi ti jáde láyé lẹ́ni ọdún méjìléláàádọ̀rún. Ìbànújẹ ni fún èmi, Laura, Barbara àti Jenna ṣùgbọ́n ọkàn wa balẹ̀ nítorípé a mọ̀ pé ọkàn tirẹ̀ pẹ̀lú balẹ̀. Ìyàwó
ààrẹ tí kò láfiwé ni Barbara Bush, bẹ́ẹ̀ni ó mú ìfẹ́ àti ètò mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà wáyé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀."
Àtẹ̀jáde míràn láti iléeṣẹ́ ọkọ rè, ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi "ẹni tí kò káàárẹ̀ nínú lílépa ìmọ̀ láàárín ẹbí."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọmọ rẹ̀ kan, Jeb Bush pẹ̀lú jẹ gómìnà ìpínlẹ̀ Florida láàárín ọdún 1999 sí 2007.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ààrẹ Donald Trump ti orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà ní, mánigbàgbé ni orúkọ arábìnrin Bush gégé bí ẹni tó sin orílẹ̀èdè àti ẹbí rẹ̀ tọkàtọkàn.













