Sunday Igboho: Bí kò bá sí ìbò láti mọ èrò Yorùbá tó fẹ́ yapa, kò ní sí ìbò òṣèlú ní 2023

Ọjọ Satide ni ilana ọmọ Oodua gbe iwọde ipolongo fun idasilẹ orilẹ-ede Yoruba Nation lọ si ilu Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti.
Nibi iwọde naa ni Igboho ti sọ pe dandan ni ki idasilẹ orilẹede Yoruba Nation waye, nitori pe aidọgba wa ninu bi ijọba ṣe n pin awọn ọrọ Naijiria, ti wọn si tun ti fi ọwọ rọ ẹya Yoruba sẹyin.
Igboho to sọrọ ni ede Yoruba sọ pe "o to gẹ. A gbọdọ duro fun ominira wa, nitori pe a ti jiya to o. Ọmọ Yoruba ni wa, a o si gbọdọ jẹ ẹru nilẹ wa."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wòlíì TB Joshua sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ lọ́jọ́ Satide tó kú - Ìjọ COAN
- Ìtàn ayé TB Joshua tó lo ọdún kan àti oṣù mẹ́ta nínú ìyà rẹ̀
- Ẹ̀mí mẹ́sàn-án tún ṣòfò ní Igangan, agbébọn jo ilè, ọkọ àti ààfin Ọba
- Ìjọba, ẹ bá mi wá ẹni tó pa ọmọ mi jáde - Ẹ̀bí olóògbé gbarata
- Aláìmọ̀kan àti òmùgọ̀ ló ń pè fún ìdásílẹ̀ Yorùbá Nation - Aregbesola
- Gbogbo ǹkan tí à ń ṣe láti jà fún ''Yoruba Nation'', ìjà àwọn bàbá wa là ń gbé - Sunday Igboho
O ni gbogbo nkan to ba gba ni awọn yoo ṣe lati gba Yoruba kuro ni abẹ isinru Fulani, ti yoo si ya kuro lara Naijiria ti yoo ba fi di ipari oṣu Kejila, ọdun 2021.
Sunday Igboho fi ẹsun kan pe gbogbo alumọni ni Naijiria ni, amọ awọn Fulani lo n ṣakoso wọn, ti wọn si tun jẹ olori ileeṣẹ ijọba gbogbo.
O ni gbogbo awọn nkan yii, to fi mọ bi ọpọlọpọ ọdọ to ti kawe tan ko fi ri iṣẹ ṣe, lo mu ki awọn o ma a polongo pe o ti to gẹ ẹ.
Ati pe ti ijọba ko ba fi ṣe idibo lati mọ eero araalu nipa iru Naijiria ti wọn fẹ, ẹya Yoruba ko ni i dibo gbogboogbo lọdun 2023.
O fikun pe ilẹ Yoruba nilo ijọba tiẹ.
O sọ pe nkan to kan lati ṣe bayii ni pe "awọn yoo wọ inu igbo lọ lati le awọn darandaran Fulani yii kuro".
- Àgbẹ̀ míì tún fara gbọgbẹ́ ìbọn ní Igangan láti ọwọ́ afurasí darandaran
- Ìjọba ẹ ṣọ́ra! gbígbégilé ojú òpó Twitter tako ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ Naijiria - Gómínà Ṣeyi Makinde
- Ìwádìí tí bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí Olùkọ́ lu akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn án pa
- Ìjọba àpapọ̀ kéde ìjìyà fún àwọn tó ṣì n lo Twitter ní Naijiria
- Mọ̀ si i nípa ìtàn eégún Gelede àti pàtàkì eégún náà sí àwọn obìnrin nílẹ̀ Yoruba
- Wo àwọn nkán tó ṣẹlẹ̀ níbi ìwọ́de Yoruba Nation tó ti wáyé sẹ́yìn
Bakan naa lo sọ nibi iwọde naa, lasiko ti o sabẹwo si aafin Èwí Ado-Ekiti, pe awọn n bọ ni Eko nitori ilẹ baba awọn ni.

Ni nkan bi aago marun irọlẹ ni Sunday Igboho ti ọpọlọpọ eniyan ti n reti nibi iwọde naa de sibẹ pẹlu ọpọ eniyan to n wọ tẹle ni ẹyin.
Ṣaaju ki iwọde naa to bẹrẹ ni awọn eeyan ti pe babi si gbagede Fajuyi Park.

Bakan naa ni wọn ṣe abẹwo si aafin Ewi Ado.
Wamuwamu si ni awọn oṣiṣẹ alaabo Amẹtẹkun, ọlọpaa, FRSC, ati awọ̀n mii duro nibi ti iwọde naa ti fẹ ẹ waye.
Àwọn olùwọ́de fún Yoruba Nation ṣe àbẹ̀wò sí àáfin Èwí ti Ado-Ekiti
Awọn oluwọde ọmọ ilẹ Yoruba labẹ asia to n pe fun idasilẹ Oduduwa Republic ti gunlẹ si ipinlẹ Ekiti fun iwọde.
Eruku ti n sọ lala ni ilu Ado Ekiti, ni igbaradi fun iwọde ipolongo idasilẹ Yoruba Nation.

Igba akọkọ re ti wọn yoo lọ si ipinlẹ naa ṣugbọn wọn ti n kaakiri awọn ipinlẹ mi ṣaaju asiko yi.
Ni nkan bi ọṣẹ meji sẹyin ni irufẹ iwọde bẹẹ waye ni ilu Akure tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo.
Ko pẹ si igba ti iwọde yi waye ni Gomina Rotimi Akeredolu figbe sita pe ki awọn eeyan sinmi ahesọ pe oun faramọ idasilẹ Oduduwa Nation.
O fọ esi yi ni idahun si ọrọ kan to gbode pe Sunday Adeyemo,Igboho, ni Akeredolu wa lẹyin awọn oluwọde Oduduwa Nation.
A ko ti mọ nkan ti yoo ṣẹlẹ loni ni ipinlẹ Ekiti ṣugbọn ko ti si ijọba ipinlẹ Yoruba kankan to kọdi iwọde awọn oluwọde Ilana Ọmọ Odua.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Kayode Fayemi
Kayode Fayemi to jẹ Gomina ipinlẹ Ekiti ti wọn n gbe iwọde bọ wa ba ni alaga ẹgbẹ awọn Gomina ni Naijiria.
Lọpọ igba lo ti fi ero ọkan rẹ nipa idasilẹ Oodua Nation han wi pe awọn ti nkan ko rọgbọ fun lo n pe fun ki wọn tu Naijiria ka.
- Èmi ò lè káwọ́ gbera kí Nàìjíríà bàjẹ́ lójú mi o, Alaafin sọ̀rọ̀ sókè
- A tí ń gbé ìgbésẹ́ láti kó àwọn tó ja bọ́ọ̀sì akẹ́kọ̀ọ́ gbà ní Ondo- Komisonna Bolaji Salami
- 'Àwọn ọmọ ogun Naijiria pa ọmọ ẹgbẹ́ ISWAP 50 ní Borno'
- Ìjọba Nàìjíríà ṣàfikún owó aàbò fáwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera
- Ilé aṣòfin Naijiria buwọ́lu òfin tí yóò fi òpin sí ìdẹ́yẹsí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ní ìwé ẹ̀rí HND








![United African Republic Nigeria: "United Africa Republic" [Nigeria] UAR - How 'Nigeria name change to UAR' go be?](https://ichef.bbci.co.uk/ace/ws/660/cpsprodpb/DD7C/production/_118800765_unitedafricanrepublicnigeriaunitedafricarepublic-nigeriauar-how'nigerianamechangetouar'gobe.png.webp)










