Security in Nigeria: Alaafin Oyo sọ̀rọ̀ lórí ìṣèjọba tó leè yọ Nàìjíríà kúrò nínú ọ̀fìn tó wà

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi III
Kabiyesi Alaafin ti ilu Ọyọ, Ikubaba yeye, Ọba Lamidi Adeyẹmi kẹta ti sọrọ sita pe ibi ti ọrọ ẹlẹyamẹya ati ẹlẹsinmẹsin de duro bayii lorilẹede Naijiria, ko fẹẹ si iru rẹ ri ninu itan orilẹede Naijiria.
Alaafin Adeyẹmi sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan eyi to fi ranṣẹ sawọn akọroyin l'Ọjọru.
Ikubaba yeye niibi ọrọ gbe de duro lorilẹede Naijiria bayii ti di ayefẹlẹ tobẹ gẹẹ ti ko si ẹni to lee ni igbagbs ms ninu awọn ileeṣẹ agbofinro gbogbo titi kan ileeṣẹ aṣọbode laiṣegbe.
- Pope Francis ṣe àyípadà òfin nínú ìjọ Aguda, ó sọ nkan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àlùfáà tó bá ní ìbálòpọ̀ kò tọ́
- Àwọn adigunjalè pa èèyàn bí mẹ́rin, níbi ìkọlu bánkì méjì ni Ikire àti Apomu
- Ìdí rèé tí Twitter kò fi le gbé ìdájọ́ Trump lé Ààrẹ Buhari
- Twitter kò dá sí ọ̀rọ̀ IPOB àti Nnamdi Kanu, bó ṣe wù wa la ṣe lè darí Nàìjíríà- Lai Mohammed
- Lẹ́kṣọ́rà fásitì FUOYE kan tún kó sí gbaga ẹ̀sùn aṣemáṣe pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́
- Agbébọn pa ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá nígbàkan rí, Christopher Deja
- Ènìyàn 28 kú lẹ́yìn ààrùn Coronaviris láàrín wákàtí 24 ní Nàìjíríà
Amọṣa Kabiyesi Alaafin Ọyọ wa pe fun agbekalẹ ijọba ipin o jupin ti oyinbo n pe ni True Federalism.
O ni irufẹ ijọba bẹẹ yoo fun awọn ipinlẹ lagbara sii.
Bakan naa lo pe fun eto ibi ko ju ibi lori yiyan awọn eeyan sipo apapọ titi kan awọn ileeṣẹ abo gbogbo.
Kabiyesi laafin ni oun ko lee kawọgbera ti orilẹede Naijiria da wo lulẹ.
Alaafin Adeyẹmi III ṣalaye pe eto iṣejọba ibi ko ju ibi Federalism ni ipilẹ ti wọn gbe orilẹede Naijiria .
O ni nibi ipade apero fun iwe ofin lọdun 1959, aba ti Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ da, leyin ti olori ẹkun ariwa nigba naa, Sadauna Ahmadu Bello fọwọ si ni gbigbe awọn ẹka bii eto ọgbin, ijọba ibilẹ ati oye jijẹ gbọdọ sọwọ awọn ijọba ẹkun gbogbo leyin to mu ki awọn idagbasoke manigbagbe lee waye nigba naa.
- Ọwọ́ ikọ̀ Amọtẹkun ba Mutiu Abdul-Rasheed, afurasí tó ń ta ẹ̀yà ara èèyàn ní Ibadan
- Ènìyàn 28 kú lẹ́yìn ààrùn Coronaviris láàrín wákàtí 24 ní Nàìjíríà
- Àwọn adigunjalè pa èèyàn bí mẹ́rin, níbi ìkọlu bánkì méjì ni Ikire àti Apomu
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ ìjọba, dẹndẹ ìyà yóò jẹ orí yín bí Nàìjíríà bá pínyà pẹ́rẹ́, toríi Yoruba Nation! - Oluwo














