FUOYE Sexual harassment: Fásitì FUOYE pàṣẹ lọ rọọ́kún nílé fún lẹ́kṣọ́rà tó ṣe aṣemáṣe pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́

Aworan idanimọ fasiti FUOYE

Oríṣun àwòrán, other

Awọn alaṣẹ Fasiti apapọ nilu Ọyẹ Ekiti, FUOYE ti ni ki olukọ agba kan nibẹ o lọ rọ ọ kun nile lori ẹsun pe o n na ọwọ aṣemaṣe ibalopọ si ọkan lara awọn akẹkọọ ni ileewe naa.

Olukọ naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Ọmọwe Mbachaga wa pẹlu ẹka imọ nipa tiata.

Oun ni iroyin nile ẹkọ giga fasiti naa ni wọn ni igbimọ tẹẹkoto ti awọn alaṣẹ ẹka ẹkọ imọ nipa Ọrọ ẹda ati ihuwasi ọmọniyan nileẹkọ giga fasiti naa gbe kalẹ rii pe ọwọ rẹ ko mọ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Atẹjade kan latọdọ awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa eyi ti agbẹnusọ fun giwa ibẹ, Foluṣọ Ogunmọdẹde ṣalaye pe ileewe naa ko ni fi aaye gba iwa aitọ.

O ni: bẹẹni oṣiṣẹ koṣiṣẹ to ba ṣe lodi si iwa ọmọluwabi ni ileewe naa bi o ti wulẹ ko mọ yoo foju wina ofin.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

Giwa ileẹkọ naa tun fi kun un pe rirọọkun ti wọn ni ki Ọmọwe Mbachaga o lọ rọọkun nile ni lati lee faaye silẹ fun agbekalẹ igbimọ ẹlẹni marun un kan ti wọn yan.

O ni giwa ile ẹkọ naa gbe igbimọ yii kalẹ lati wadii ẹsun ti wọn fi kan an lọna ati lee mọ otitọ gbogbo to rọ mọ.

Àkọlé fídíò, 'Èmi ọmọ Ikorodu ọ̀ga, ọmọ aṣalẹ̀ jẹ́jẹ! Wo bí àwọn ọmọdé tó "tuush" yìí ṣe ń fi oríkì Yorùbá dábíra

Bakan naa ni Giwa ileewe naa tun paṣẹ fun adari ẹka ẹkọ imọ nipa Ọrọ ẹda ati ihuwasi ọmọniyan nileẹkọ giga fasiti naa lati ṣe iwadii lori irufẹ ẹsun nina ọwọ aṣemaṣe ibalopọ si ọkan lara awọn akẹkọọ ni ileẹkọ naa.

O ni ki wọn tun ṣayẹwo irufẹ ẹsun bẹẹ gbogbo ti wọn tun fi kan olukọni miran ni ẹka ẹkọ naa.

Àkọlé fídíò, Simple tricks to identify designer shoes: Ṣe ìwọ lè wọ bàtà #2 mílíọ̀nú