Ondo: Nítorí ikú ọlọ́pàá, àwọn ọ̀dọ́ lé kábíyèsí jáde láàfin l'Ondo

Awọn ọdọ ni Itaogbolu

Oríṣun àwòrán, The news track.com.ng

Awọn ọdọ ilu Itaogbolu ni ijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ nipinlẹ Ondo ti le kabiyesi wọn kuro laafin.

Eyi waye lẹyin ti ọlọpaa kan ti orukọ rẹ n jẹ Ayọ Oloyede kagbako iku ninu ijamba ọkọ kan to waye.

Gẹgẹ bi iroyin abẹle to tẹ BBC News Yoruba lọwọ ṣe sọ, awọn ọdọ naa fura pe iku ọlọpaa naa kii ṣe ojulasan.

Bi o tilẹ jẹ pe ibeere ọpọlọpọ ni pe ki lo kan kabiyesi kan iku ọlọpaa to ku ninu ijamba mọto?

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe awọn ọdọ ilu naa ti inu mbi fi ikanra le kabiyesi Ogbolu tilu ItaOgbolu, Ọba Idowu Fabọrọde kuro laafin lori ẹsun pe o kuna ninu ojuṣe rẹ lati daabo bo awọn ọmọ ilu naa.

Àkọlé fídíò, Adebayo Murital David: Gbogbo iṣẹ́ tó ń múni là láyé wá láti ọpọlọ ni kìí ṣe agbára

Ọlọpaa naa ti wọn ni o n ṣiṣẹ ni ẹka igbogun ti iwa ẹgbẹ okunkun nileeṣẹ ọlọpaa, Anti-cultism unit to wa nilu Akurẹ wale wa ki iya rẹ gẹgẹ bi awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ṣe sọ. Ipada rẹ si ilu Akurẹ lo ti kagbako ijamba to sọ di ero ọrun.

Awọn ọdọ ilu naa la gbọ pe wọn ni kii ṣe oju lasan ni iku naa ati pe eeyan darandaran ti ọpọlọpọ awọn araalu nifẹ ni oloogbe naa,