EFCC mú ọmọ Yahoo tó fẹ́ fi Bitcoin ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí iye rẹ̀ tó 44 mílíọ́nù

efcc

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC

Ileeṣẹ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC, ẹka ti ipinlẹ Eko ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi ọmọ Yahoo kan to gbiyanju lati ra ọkọ ayọkẹle SUV ti iye rẹ to miliọnu mẹrinlelogoji pẹlu Bitcoin.

EFCC fẹsun kan afurasi naa, Tobiloba Aramide Ogundiyan pe o yi owo to ri nidi iṣẹ jibiti pada si owo Bitcoin.

Oṣiṣẹ EFCC kan to ba awọn akọroyin sọrọ ni "Ọna ẹburu lo gba ri owo rẹ, o si gbiyanbju lati fi owo naa ra ọkọ ayọkẹlẹ SUV ti iye rẹ to miliọnu mẹrinlelogoji ni ṣọọbu ti wọn ti n ta ọkọ ni Lekki."

Wọn fi panpẹ ofin mu afurasi ọhun pẹlu awọn meje miran lagbegbe River View Estate to wa ni Lekki fun oniruru ẹsun to jọ mọ lilu jibiti ori ayelujara.

Awọn afurasi mii ti EFCC tun mu ni Samson Alabi Afolabi; Adebayo Dolapo Olumide; Daniel Boluwatife Akinwunmi; Moses Segun; Kelechi Thankgod Felix; Adeleke Godwin Tofunmi ati Adewale Dapo Victor.

EFCC ni wọn ka awọn ohun ìní olowo iyebiye lọwọ wọn bii ẹrọ ilewọ, ẹrọ ayarasbiaṣa alagbeka, oriṣiriṣi ọkọ olowo iyebiye, ẹṣọ ara ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ileeṣẹ naa ni yatọ si jibiti ori ayeluja, awọn afurasi ọhun tun n lu jibiti lọna miran.

Àkọlé fídíò, Democracy day 2021: Kí ni Nàìjíríà ti jèrè lára gbogbo ààrẹ tó ti jẹ látọdún 1999?