Cultism in Kwara: Ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn bẹ́ sódò láti bọ́ lọ́wọ́ ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Okasanmi
Àwọn ìpánle kan gba ìgboro nílu Ilorin lórí ikú ọdọ́mọkùnrin kan tó kú, Musbau Saheed tó bẹ́ sómi lágbègbè Abdulazeez Attah ní Ilorin.
Musbau bẹ́ sómi ń gbìyànjú láti sá fún ọlọ́pàá tó fẹ́ mu lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn jà.
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn náà láti orítà mẹ́ta Agbo-Oba ti wọ́n sì ti gbogbo òpópónà ti wọ́n sì n sun táyà tí wọ́n sì padpa lọ sí agbégbe olu ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ni agbègbè GRA.
- Adeherself sọ̀rọ̀ sókè lẹ́yìn tí Cute Abiola ṣe ìgbéyàwó ìdánkọ́nkọ́ l'Ogbomoso
- Chelsea pòfo nínú ìdíje FA Cup, báwo ni Champions League yóò ṣe rí pẹ̀lú Man City?
- Tí Benue kò bá ní Sunday Igboho tIẹ̀, ìṣekúpaní yóò tẹ̀síwájú - Reno Omokri
- Góòlù ₦14bn, ilé $80m la rí gbà padà lọ́wọ́ Diezani Alison-Madueke - EFCC
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Greenfield tí wọ́n jí gbé ní Kaduna gba òmìnira lẹ́yìn tí àwọn òbí wọn san "180 mílíọ́nù naira"
Ìròyìn sọ pé Saheed Musbau wà lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tí wọ́n ti dá wàhàlá sílẹ̀ lọ́jọ́ Eti. Ti Musibau si bẹ́ sódò lásìkò tí àwọn ọlọ́pàá fẹ́ mú u.
Bákan náà ni ìròyìn sọ pé ọkùnrin náà ti wà lára àwọn tí wọ́n n wá tẹ́lẹ̀, sùgbọ́n lásìkò tó fẹ́ ra sìgá ni agbègbè Baboko nígbà tí ọlọ́pàá rí tó si fi panpẹ́ sí lọ́wọ́ tó sì mu sí inú mótò.
Sáájú ni àwọn ni àwọn ọlọ́pàá ti fi orúkọ rẹ̀ sílẹ̀ pé ó wà lára àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn tí wọ́n ń wá.
Lásìkò tí wọ́n mu yìí ló sá tí wọ́n sì ń lé ló bá bẹ́ sínú omí, sùgbọ́n ìgbà tí wọ́n yóò fi dóòlà rẹ̀ ó tí kú.
Iròyìn sọ pé gbogbo ìgbiyànjú àwọn pánapana láti dóòlà rẹ̀ ló jásí pàbó títí ti ọkùnrin Hausa kan tó jẹ́ sóbàtà ló padà rí yọ.
Wọ́n sáré gbe lọ sí ilé ìwòsàn gbogbonise ni Ilorin, sùgbọ́n ẹlọ́mi ti gbà á kí wọ́n tó gbé e de ibẹ̀.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara, SP Ajayi Okasanmi sọpé wọn gbìyànjú láti kọlu Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn ti wọ́n ti mu àláafíà pàdàbọ̀ sí agbègbè Suurulere, Baboko àti Oja Tuntun ní ìlú Ilorin.
Okasanmi ni àwọn tó n gbìyànju láti ja jẹ́ ọ̀daràn àti ọmọ ẹlẹgbẹ́ òkùnkùn.
Ó ni àwọn méjì ni wọ́n mú sùgbọ́n nígbà tí wọ́n ń ko wọn lọ si àga ọlọ́pàá ló sáre kóinú odo tó wà ni agbègbè náà.
Bákan náà ni ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ti ṣe àbẹ̀wò sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ tó náà tó sì pè fún ìwádìí.
- Arúmọjẹ lásán ni lọkọ-láya tí èmi àti Cute Abiola jọ́ ń ṣe tẹ́lẹ̀, ìyàwó rẹ̀ ti dé- Adeherself
- Ariwo ẹkún sọ lẹ́yìn tí wọ́n ṣàwárí òkú akẹ́kọ̀ọ́ 215 nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ yìí
- Bí Ààrẹ Buhari bá parí sáà rẹ̀ tán ni ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria yóò mọ rírì iṣẹ́ tó ń ṣe - Ìjọba àpapọ̀
- Ìjà Awolowo, Akintola àti ogun 'Wẹtiẹ', ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wa?

















