Canada ń ṣọ̀fọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n rí òkú akẹ́kọ̀ọ́ 215 nílé ẹ̀kọ́ kan

Kamloops Indian Residential School

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ijọba ilẹ Canada ti sọrọ lẹyin ti wọn ri oku awọn akẹkọọ okòólénígba dín marun (215) nile ẹkọ kan ti wọn ti gbe ti pa.

Adari ijọba orilẹ-ede naa, Justin Trudeau sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ eyii to ba ijọba oun ninu jẹ gidi.

Awọn akẹkọọ ti wọn ri oku wọn naa jẹ akẹkọọ Kamloops Indian Residential School to wa lagbegbe British Columbia, eyii ti wọn gbe ti pa lọdun 1978.

Wọn da ile ẹkọ naa silẹ lati kọ awọn eeyan agbegbe ọhun lọna ati gbe igbe ye ọtun lọdun naa lọhun.

Ile ẹkọ naa jẹ eyii ti awọn akẹkọọ n gbe gẹgẹ bii ijọ Katoliiki ṣe ṣagbekalẹ rẹ lọdun 1890, awọn akẹkọọ rẹ si le ni ẹẹdẹgbẹta nigba ti yoo fi di aarin ọdun 1950.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Iroyin ni ẹrọ kan to ṣayẹwo ayika ile ẹkọ naa lo ṣawari oku awọn akẹkọọ ọhun nibi ti wọn sin wọn si ninu ọgba ile ẹkọ naa.

Kamloops Indian Residential School

Oríṣun àwòrán, Reuters

Obinrin kan to sọrọ lorukọ awọn aṣoju agbegbe naa, Casimir sọ fun awọn akọroyin pe ko si akọsilẹ kankan pe awọn akẹkọọ naa poora.

O ni "Ọmọde ni awọn akẹkọọ naa, koda, ọmọ ọdun mẹta wa lara wọn."

Àkọlé fídíò, Democracy day 2021: Kí ni Nàìjíríà ti jèrè lára gbogbo ààrẹ tó ti jẹ látọdún 1999?

"Ṣugbọn gẹgẹ bi oun ti a mọ, ko si akọsilẹ kankan pe ẹnikẹni ninu awọn akọkọọ ọhun ti sọnu ṣaaju."

Adari agbegbe Bristish Columbia Lisa Lapointe sọ fun ileeṣẹ iroyin ilẹ Canada, CBC pe, awọn ti gbe iwadii dide lọna ati tu iṣu de isalẹ ikoko iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Bode George: òòtọ́ ni ìkìlọ̀ Obasanjọ ati Soyinka