#BenueUnderAttack: Gómìnà Benue ní kí aráàlú gba àṣẹ ìbọn lílò bí agbébọn ṣe pa èèyàn 42

Benue

Oríṣun àwòrán, Twitter/#BenueUnderAttack

Ni aarọ ọjọbọ ni ariwo tun sọ pe awọn gende agbegbọn ti wọn fura si bii darandaran tun da ẹmi eeyan mejilelogoji legbodo nifọnna-fọnsu.

Ninu ọrọ tirẹ nipa isẹlẹ naa, Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom rọ awọn ara ilu lati wa ibọn fi da abo bo ara wọn nitori o ti to gẹ.

''Emi ko ni kede awọn eniyan ti awọn agbebọn Fulani darandaran n pa mọ, nibayii ki awọn eniyan gba aṣẹ lọwọ ijọba ibilẹ lati lo ibọn ilewọ, ki wọn si da abo bo ara wọn.''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Idi si ree ti gbajugbaja ajafẹtọ ọmọniyan, Reno Omokri se woye pe awọn eniyan ipinlẹ Benue nilo iru eniyan bii Sunday Igboho, lati dawọ ipaniyan to n lọ lọwọ duro nibẹ.

Iroyin lo n ja sita loore koore nipa bi awọn agbebọn ko se jawọ ṣiṣe ikọlu nipinlẹ Benue lati bi ọjọ melo sẹyin, ti ọpọlọpọ ẹmi si ti ṣofo.

Ọrọ ti Reno Omokri sọ loju opo Twitter rẹ

Oríṣun àwòrán, @renoomokri

Reno Omokri, to jẹ oluranlọwọ tẹlẹ fun aarẹ Goodluck Jonathan ni, ọna abayọ si iṣekupani yii ni ki awọn eeyan Benue naa ni akinkanju eniyan bii Sunday Igboho.

O fikun pe aarẹ Buhari ko ni sọ nkankan ti awọn eniyan ba ku, amọ ti wọn ba pa awọn maalu, aarẹ Buhari a fọhun jade.

O ni nitori naa ni awọn eniyan se nilo ati ja fun ara wọn, nitori ko si ẹni ti wọn le e gbe ọkan le ninu ijọba.

Bakan naa, awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si ni fi ẹhọnu han lori ayelujara pẹlu hashtag#BenueUnderAttack, nitori aworan ọgọọrọ awọn eniyan ti ẹmi wọn ti ba iṣẹlẹ naa lọ, ti wọn ri.

Nibayii, o ti le ni ẹgbẹrun eniyan ni ọna ọgọrun ti o ti bu ẹnu lu iṣẹkupani to n waye ni ilu Benue naa loju opo Twitter.

Ọrọ ti Ayisa Yusuf sọ loju opo Twitter rẹ

Oríṣun àwòrán, @Aisha Yusuf

Lara wọn ni afajẹtọ Aisha Yesufu to sọ wi pe ẹmi awọn eniyan ni Benue pọn dandan, o si kesi ijọba lati da abo bo awọn eniyan.

Aisha Yesufu ni ẹmi awọn eniyan kan ko ṣọwọn ju ẹmi awọn eniyan miran lọ nitori naa ki ijọba ye dari apa kan, da ikan si.

Bakan naa ni gbajugbaja osere ni Naijiria ni ọgbẹ ọkan lo jẹ fun oun pẹlu awọn aworan iṣekupani awọn eniyan lọgọọrọ ti oun ri lori ayelujara nitori awọn agbebọn to yabo awọn ilu wọnyii, ti wọn si pa wọn bii ẹran.

O ni lati igba ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ni oun ko ti le ṣe iṣẹ oun bii iṣẹ nitori ibanujẹ ọkan lo jẹ fun oun lati ri oku awọn eniyan lai ṣẹ, lai ro.

Ọrọ ti Kate Hebshaw sọ loju opo Twitter rẹ

Oríṣun àwòrán, @HenshawKate

Awọn ero miran to fi ero wọn han kesi ijọba Buhari lati pese aabo to peye fun awọn eniyan, ki aarẹ Buhari si sọrọ lasiko to yẹ, kii ṣẹ igba to ba wu u.