Ghost thief caught in Zimbabwe: Ọwọ́ tẹ ọkùnrin tó n múra bí òkú ọrùn láti ja àwọn èèyàn ní olè

Ọkunrin to n fi aṣọ oku jale

Oríṣun àwòrán, @daddyhope

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Yoruba sọ pe ọjọ gbogbo ni ti ole, amọ ọjọ kan ni ti olohun.

Bẹẹ gan ni ọrọ ri fun ọkunrin afurasi ole, alọ kolohun kigbe kan lasiko ti ọwọ tẹ lẹyin ọjọ pipẹ to ti ma n ja awọn eeyan lole.

Amọ nkan to jẹ iyalẹnu fun gbogbo eniyan ni pe ọna ara, ọna to yanilẹnu ni ọkunrin naa n gba ja ole tiẹ, to bẹẹ ti ọwọ ko fi tẹ ẹ titi di akoko yii.

Awọn ileeṣẹ iroyin ni Zimbabwe sọ pe niṣe ni ọkunrin naa ma n mura bi oku, lati ja awọn eniyan ilu Gutu, ni agbegbe Masvingo, lorilẹ-ede Zimbabwe, to wa ni Ila oorun Africa, lole ninu ile wọn.

Wọn ni ọkunrin hun yoo wọ aṣọ kan ti wọn sẹ bii egungun oku gbigbẹ, eyi ti wọn n pe ni 'skeleton' ni ede Gẹẹsi. Aṣọ naa ma n bo gbogbo ara rẹ lati ori titi de atẹlẹsẹ.

Àkọlé fídíò, King Sunny Ade's son: Ohùn orin bàbá mi nìkan kọ ni l’Ọlọrun fún mi, ijó bíi kòkòrò ni ṣáá

Ṣebi ẹni ija o ba, lo n pe ara rẹ ni ọkunrin.

Ni kete ti 'oku' ọkunrin naa ba ti wọle tọ ẹni to fẹ ja lole, ni onitọhun yoo fi ẹsẹ fẹẹ lai duro wẹyin.

Igbagbọ awọn ti ọkunrin yii ti ja lole ni pe oku gidi lo wọle tọ wọn.

Eyi ṣee ṣe ko ri bẹẹ, nitori igbagbọ to wa nilẹ Afirika ni pe ẹni to ti ku le pada wa si aye lati farahan awọn eniyan rẹ, tabi gba ẹsan lara ẹnikẹni.

Akudaaya ni Yoruba n pe e.

Àkọlé fídíò, Ifayẹmi Elebuibon: Ọ̀pọ̀ òkú ló ń rìn káàkiri ìlú Èkó, Ìbàdàn, Òṣogbo

Ni kiakia si ni 'oku' naa yoo ko gbogbo nkan to ba wu u ninu ile ẹni naa to ti salọ.

Amọ, okete boru mọ ọ lọwọ, lẹyin ti awọn eeyan kan gbiyanju lati 'ṣe bi ọkunrin', ti wọn si pinnu lati tu 'oku' naa ni aṣọ wo.

Bayii ni ọkunrin naa ṣe ri lẹyin ti wọn bọ aṣọ oku to fi bo oju

Oríṣun àwòrán, @daddyhope

Àkọlé àwòrán, Bayii ni ọkunrin naa ṣe ri lẹyin ti wọn bọ aṣọ oku to fi bo oju

Iyalẹnu si lo jẹ nigba ti wọn ba alaaye eniyan labẹ ẹku.

Gbajugbaja akọroyin kan ni Zimbabwe, Hopewell Chin'ono, to fi iroyin naa sita sọ pe ọwọ ti tẹ afurasi ole naa bayii. O si ti wa ni agọ ọlọpaa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post