Fete Gede: Wo àwọn èèyàn tó ń jí àwọn òkú láti bèèrè ààbò ẹ̀mí

Ajọdun awọn oku

Oríṣun àwòrán, Travel Noire

Airin jinna, lai ri abuke ọkẹrẹ, t'eeyan ba rin jinna, yoo ri ẹja to yarọ ninu ibu.

Awọn eeyan kan ma ree, ti wọn maa n ba oku sọrọ lọdọọdun fun aabo ẹmi, owo, ọmọ ati fawọn ipese nnkan miran.

Ọdun awọn to ti ku ti wọn maa n pe ni Fete Gede, jẹ ọkan lara ayẹyẹ to ṣe pataki julọ fawọn ẹlẹsin ibilẹ to n lo oogun dudu, ti wọn n pe ni Voodoo.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ayẹyẹ ọhun to maa n waye lọdọọdun, ni wọn ti maa n ṣe ajọyọ lori awọn ẹmi airi, awọn to wa lajule ọrun at'awọn oku lorilẹede.

Ajọdun awọn oku

Oríṣun àwòrán, Travel Noire

Ọdun naa ti wọn maa n ṣe lọjọ meji akọkọ ninu oṣu kọkanla, lawọn eeyan maa n lo lati wa agbara, abo ati ibaṣepọ ọtun pẹlu awọn oku.

Ọpọ eeyan lo maa n lo asiko yii lati ba awọn eeyan wọn to ti ku sọrọ, awọn ti wọn jọ ni asọti ọrọ papọ ki iku to mu wọn lọ.

N ṣe ni ẹmi awọn oku maa n ba le awọn eeyan lori nibi ajọdun naa.

Awọn ẹlẹsin ibilẹ to n lo oogun dudu Voodoo, to jẹ ọkan lara awọn ẹsin to ti wa nilẹ Afirika tipẹ, lo ni ajọdun yii.

Ajọdun awọn oku

Oríṣun àwòrán, Travel Noire

Ọpọ ninu awọn eeyan to n se ajọdun awọn oku yii, lo wa lati orilẹ-ede Benin, awọn mii wa lati iran Yoruba ni Naijiria, awọn kan lati Ghana, nigba ti awọn mii lati ẹkun ijọba Kongo.

Koda, awọn ẹlẹsin Kristẹni gan an maa n darapọ mawọn to n ṣe ajọdun yii lorilẹede Haiti.

Orilẹ-ede Haiti ni ẹsin yii ti bẹrẹ ati apa ilẹ Caribbean, nibi tawọn eeyan ti wọn ko lẹru lati iwọ oorun Afirika wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fun ọpọ ọdun bayii, ẹsin Voodoo ti dapọ mọ ẹsin Kristẹni ati Musulumi.

Ajọdun Fete Gede bẹrẹ pẹlu awọn to maa n mura bi ẹmi airi ti wọn maa n pe ni Loas.

Ajọdun awọn oku

Oríṣun àwòrán, Travel Noire

Awọn mii maa n wọ aṣọ funfun, ti wọn o si maa jo lọ si oju saare ti wọn n sin oku, si pẹlu ẹbun ti wọn fẹ fun awọn oku.

Bakan naa ni wọn maa n gbe ounjẹ dani fawọn oku fun aabo wọn lori awọn alaaye.

Ajọdun yii maa n gba okun ati agbara awn to ba n se e nitori ẹmi awọn oku maa n gun wọn, ti ẹmi awọn oku naa yoo si dabi ti alaaye.

Ajọ̀dun awọn oku yii lo maa n se pẹki n pẹki pẹlu ayajọ ọjọ awọn oku ninu ẹsin Kristiẹni, ti wọn n pe ni All Saints Day.

Ajọdun awọn oku

Oríṣun àwòrán, Travel Noire

Wọn tun maa n fi ajọdun yii ṣe iranti Papa Gede, ẹni ti wọn gbagbọ pe oun lo kọkọ ku, ti o sí ṣaaju awọn oku miiran lọ si ilẹ tuntun tii ṣe ibugbe awọn oku.

Wọn tun maa n fi oríṣìíríṣìí nkan pa ara wọn to fi mọ fifi ata soju ara wọn, nigba ti akoko wọn ba to lati fawọn oku ni ẹbun.

Awọn eeyan tun maa n lo ajọdun Fete Gede lati beere fun owo, ẹmi gigun, ọmọ ati abo lọwọ awọn ẹmi airi.