Niger School Fire: Àlàyé rèé lórí bí iná ṣe jó ogún akẹ́ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ pa níléèwé

Ileewe

Awọn ẹbi ati ara awọn akẹkọọ ogun ti bẹrẹ si ni ṣọfọ lẹyin ti ijamba ina gbẹmi awọn ọmọ wọn ni ileewe.

Iṣẹlẹ naa waye ni ileewe alakọbẹrẹ ni agbegbe Pays Bas, ni ilu Niamey to jẹ olu ilu orilẹede Niger.

Akọrọyin BBC, Tchima Illa Issoufou ni ilu Niamey ni, ina naa bẹrẹ ni ẹnu ọna ileewe naa to ni akẹkọọ to le ni ẹgbẹrin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Titi di asiko yii, koi tii si ẹni to mọ ohun to fa iṣẹlẹ ina naa.

Awọn akẹkọọ

Amọ, ileeṣẹ panapana to wa si ibi iṣẹlẹ naa ni, bi wọn ṣe kọ awọn yara ikẹkọọ naa bii ahere papọ, lo mu ki ina naa gba gbogbo ileewe naa.

Olori ileesẹ panapana Sidi Mohamed ni, awọn oṣiṣẹ oun tete de ileewe naa lati pa ina to n jo ran-in ran-in ọhun, ki awọn to ri pa.

Awọn akẹkọọ
Àkọlé àwòrán, Awọn ẹbi ati ara awọn akẹkọọ ogun to ba iṣẹlẹ ijamba ina lọ ni ile iwe naa ti bẹrẹ si ni ṣọfọ.

''Yara ikawe mejilelogun lo jona raurau pẹlu awọn akẹkọọ ogun to ha si inu yara ikawe naa, ti wọn si ku.''

''Ko tun si ọna pajawiri kankan fun awọn akẹkọọ lati gba jade, ti awọn miran tilẹ gun ogiri, lati raye sa asala fun ẹmi wọn.''

''O si ṣeni laanu wi pe awọn akẹkọọ ọmọde ti wọn nilo iranwọ to ha si inu ina ọhun lo ku, ninu ijamba ina naa.''

Awọn akẹkọọ

Bakan naa ni Sidi Mohamed ni awọn ileewe yii ti wọn kọ si opopona, ti atẹkun lile si n fẹ pẹlu ohun to ṣe ijamba fun awọn ọmọde, ni ile alakọbẹrẹ naa.