PDP South West: Fayose ní àwọn aṣojú dìbò ju bó ṣe yẹ níbi ìpàgọ́ PDP

Gomina Seyi Makinde ati awọn oludibo

Oríṣun àwòrán, @OfficialSeyiMakinde /Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan, Ayodele Fayose, ti fẹ̀sùn kàn pe wọn di ibo kọjá bo ṣe yẹ nibi ipagọ ẹka ẹgbẹ oṣelu PDP ni Guusu Ìwọ̀ oòrùn Naijiria, to waye nilu Osogbo lọjọ Aje.

O ni sugbọn oun ti pinnu lati gboju kuro, fun anfaani ẹgbẹ.

Nibi idibo naa ni Amb. Taofeek Arapaja, oludije ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde, ṣe atilẹyin fun, ti bori pẹlu ibo 343.

Alatako rẹ to jẹ ti Ayodele Fayose, Eddy Olafeso, ni ibo 330.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Esi ibo naa mu ki Arapaja di Igbakeji Alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, fun ẹkùn Ìwọ̀ Òòrùn Gusu Naijiria.

Fayose, ninu awọn ọrọ to kọ sori ayelujara Twitter rẹ lọjọ Aje sọ pe oun ti foju fo gbogbo 'mago-mago' to wu ko waye nibi idibo naa fun anfaani ẹgbẹ.

Ọrọ ti Ayodele Fayose kọ

Oríṣun àwòrán, @GovAyoFayose

"Nitori naa, a gbọdọ lo okun ati awọn nkan ti a ní lati tun ẹgbẹ wa kọ́.

" Ibo 343 ti Arapaja ni, ati 330 ti Olafeso ni fihan pe awọn mejeeji lo ni l'agbara. Ẹgbẹ si gbọdọ lo anfaani naa bayii. "

Sugbọn ṣa, Gomina Makinde sọ pe idibo naa lọ deedee ati ni alaafia.

Ninu ọrọ ti oun naa kọ sori Twitter, o ni igbesẹ imupadabọsipo ẹgbẹ PDP ti bẹrẹ.

Ohun mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Taofeek Oladejo Arapaja

Alhaji Arapaja Taofeek

Oríṣun àwòrán, Alhaji Arapaja Taofeek/Facebook

Taofeek Oladejo Arapaja jẹ ọkan Pataki lara awọn oloṣelu Naijiria lati ipinlẹ Oyo, oun si ni Igbakeji Gomina Ipinlẹ Oyo tẹlẹ,lasiko isejọba Adebayo Alao-Akala lati ọdun 2007.

Wọn bi Arapaja ni ọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla, ọdun 1958.

O kawe nile ẹkọ girama Lagelu, niluu Ibadan, o si kawe gboye ni fasiti Wales, nilẹ Gẹẹsi.

Ko to darapọ mọ oselu, o ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ nipinlẹ Oyo, iyẹn Teaching Service Commision, lọdun 1992.

Arapaja ṣe alaga ijọba ibilẹ ila oorun Ibadan lẹẹmeji ọtọtọ, laarin ọdun 1996 si ọdun 2003.

Lẹyin naa ni wọn yan si ipo aṣoju-ṣofin fun ẹkun guusu ila-oorun ati ariwa ila-oorun Ibadan laarin ọdun 2003 si 2007.

Àkọlé fídíò, Egbejila Fish Village: Àwọn ọlọ́sìn ẹja ní àwọn fi iṣẹ́ báńkì sílẹ̀ wá ṣe ọ̀sìn ẹja ni

Ọdun 2007 ni wọn fi ibo gbe wọle gẹgẹ bii igbakeji gomina ipiinlẹ Oyo labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Lọdun 2011, Aarẹ Goodluck Jonathan yan sipo aṣoju ijọba Naijiria si orilẹ-ede Jordan ati Iran ki saa ijọba naa to dopin lọdun 2015.

Inu oṣu kẹrin ọdun 2021 yii ni Taofeek Oladejo Arapaja fi ẹyin Eddy Olafeso gbolẹ, to si jawe olubori gẹgẹ bii igbakeji alaga ẹgbẹ PDP ni iha iwọ oorun-guusu Naijiria.

Musulumi ni Taofeek Oladejo Arapaja, o si ni iyawo atawọn ọmọ.

Amin iyasọtọ kan

Makinde fàgbà han Fayose, Arapaja fi ẹyin alátako janlẹ̀ láti dì alága PDP ní SW

Aworan Seyi Makinde ati Taofeek Arapaja

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, ni ẹkun iwọ oorun Guusu ti dibo yan igbakeji gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo, Taofeek Oladejo Arapaja gẹgẹ bi alaga wọn tuntun.

Ikede iyansipo naa foju han lẹyin idibo to waye nibi ipade apero ẹgbẹ naa ni ilu Osogbo lọjọ Aje.

Arapaja, to jẹ aayo Gomina Seyi Makinde, to si tun fi igba kan jẹ igbakeji Gomina ni ipinlẹ Oyo fẹyin alatako rẹ, Dokita Eddy Olafeso janlẹ pẹlu ibo 343 si 330 .

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alaga eleto idibo nibi ipade apero naa, Benson Abounu ati alaga igbimọ alamojuto Osita Chidoka, lo seto kika ibo ọhun.

Gomina Seyi Makinde ko jẹ ko pẹ pupọ lẹyin aṣeyọri yii, to fi fi ọrọ ikini ranṣẹ si Arapaja.

Loju opo Facebook rẹ, o kọ sibẹ pe asiko to bayi lati bẹrẹ atunto ati igbelarugẹ ẹgbẹ PDP pada.

Aworan Gomina Seyi Makinde nlasiko idibo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Awọn aṣoju ẹgbẹ wọnyii ni yoo maa ṣoju ẹgbẹ PDP bọrọ ba kan gbogbo Naijiria.

Lara awọn ipinlẹ ti ẹgbẹ oṣelu PDP yii ti fẹsẹ mulẹ ni Oyo wa, ti Gomina Seyi Makinde ṣi n gbiyanju lati pẹka ẹgbẹ naa de awọn ipinlẹ mii ni ẹkun iwọ oorun Guusu Naijiria.

Amin iyasọtọ kan

Gbà fún ọ̀gá ẹ! Fayose gbà pé Makinde ni olórí ẹgbẹ́ PDP nílẹ̀ Yorùbá

Seyi Makinde ati Ayodele Fayose

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán, Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayodele Fayose sọ bẹẹ nibi ipade gbogboogbo ẹgbẹ oṣelu PDP to waye ni ilu Osogbo.

O dabi ẹni pe awuyewuye iwọ o jumi, emi o ju ọ laarin Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ati Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ ri, Ayodele Fayose ti f'ẹnu ko sibi kan bayii.

Eyi ko ṣẹyin fidio kan to n ja ranyin lori ẹrọ ikansiraẹni Twitter nibi ti Fayose ti tuba fun Seyi Makinde.

Fayose sọ ninu fidio naa lori Twitter pe Makinde ni olori ẹgbẹ oṣelu PDP lapa iwọ oorun Naijiria.

Nibi apẹjọ ẹgbẹ oselu PDP to n lọ lọwọ ni ilu Osogbo ni ipinlẹ Ọyọ ni Fayose ti sọ ọrọ naa.

O ni awọn to n da awuyewuye silẹ laarin Makinde ati oun kii ṣe awọn to nifẹ PDP tọkantọkan.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

''Seyi Makinde, ọrẹ mi, ẹnikeji mi ati pẹlu ifẹ Ọlọrun, adari wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP''

''Mo dupẹ fun atilẹyin awọn asaaju ni ẹgbẹ oṣelu PDP ti ko jẹ ki ẹgbẹ oṣelu naa daru''

''Ibeere ti ọpọ eniyan n beere ni wi pe tani olori ninu ẹgbẹ oṣelu PDP?''

''Amọ mo fi n da yin loju wi pe Seyi Makinde ni olori wa.''

''Ẹyin alatilẹyin wa, ẹ ma da ija silẹ laarin wa, ki ẹgbẹ oselu PDP le ni ilọsiwaju ni iṣejọba orilẹede Naijiria''

Ni ọpọ igba ni ariyanjiyan ti n waye lori ẹni ti yoo dipo olori mu ni ẹgbẹ oṣelu PDP laarin Ayo Fayose ati Seyi Makinde.

Bakan naa ni iroyin fikun wi pe ipade gbogboogbo naa lọ ni irọwọrọsẹ.