Foluke Daramola: Toyosi Adesanya sọ òkò ọ̀rọ̀ sáwọn tó ń pe eléré tíátà ní aṣẹ́wó

Ẹ jọ́wọ́ ẹ fi Foluke sílẹ̀ pẹ̀lú ǹka tó yà láàyò
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lórí ọ̀rọ̀ ìbanilórúkọ jẹ́ tí Foluke Daramola fí ké gbàjare lójú òpó instagram rẹ̀ láìpẹ́ yìí, ọ̀kan nínú àwọn gbájúgbajà òṣèré tíátà míràn tún ti bọ́ síta lórí ọ̀rọ̀ náà.

Toyosi Adesanya, gbajumọ osere mii to bọ sita naa ni gbogbo ẹni ti ìṣesí Foluke bá n bí nínú, kí wọ́n lọ wá ǹkan ṣe si.

Toyosi sọ̀rọ̀ yìí lójú òpó instagram Foluke Daramola, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àdarí ẹgbẹ́ Tampan.

O ni gẹ́gẹ́ bi ìṣẹ́ tí àwọn gbà, kò di dandan nígbà ti àwọn àgbà ẹgbẹ́ bá dí olóògbé, kí àwọn tó ṣe ojúṣe tó yẹ fun wọn.

Toyosi ni ìgbésẹ̀ Foluke Daramola ni láti mú inú àwọn ènìyàn náà dùn lásìkò tí wọ́n wà láyé, à ti pé àwọn kìí ṣe oore tí wọ́n yóò lọ máa pòréré rẹ̀ lórí ayélujára.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Gbajúgbajà òṣèré náà ni láti bi ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ṣẹyìn ni àwọn tí máa n ran ara àwọn lọ́wọ́, tó bá kù díẹ̀ káàtó fún ọmọ ẹgbẹ́.

"Ṣe o di ìgbà tí àwọn àgbà yìí bá kú tán, kí a tó tọ́jú wọ́n ni, ǹkan tí a bá lẹ́nu iṣẹ́ nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ ni à ń ṣe"

Ó ní òun rọ àwọn olólùfẹ́ àti olùwòràn eré títà, láti máṣe mú ǹkan ṣú àwọn nitori awọn n gbìyànjú láti ṣe oore, o ni bákan náà ni ọ̀pọ̀ àwọn mííràn nínú agboolé tíátà pẹlu n se oore.

Toyosi wa kesi awọn eeyan to n sọrọ odi nipa Foluke pe "tí ìwọ́ bá tilẹ̀ ti ro ara rẹ pín pé o ko lè jẹ́ ènìyàn mọ́, ṣe o mọ iye ọdún tí àwa ti lò, kí a tó ní orúkọ tí a ni lónìí ni?

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa: Kí ni Ìjálá láàrin àwọn ewì alohùn àti bí wọ́n ṣe ń sun-ún?

Àìmọye ènìyàn ló ti ni orúkọ jùwá lọ lásìkò tí à ti bẹ̀rẹ̀ àti àwọn ti a ti lọrúkọ jùlọ láti ìgbà tí a ti bẹ̀rẹ̀ yìí."

Toyosi ni òun ni Foluke Daramola yan gẹ́gẹ́ bi akọ̀wé ẹgbẹ́ ajọ náà nígba to ṣe ìdásìlẹ̀ rẹ̀ lọ́dún 2019, àpò ara rẹ̀ sì ló tí mú owó tó fi n ràn àwọn arúgbó náà lọ́wọ́"

" Tí ìwọ́ bá ni àgbàlagbà tàbi òbí nílé rẹ, tí o kọ̀ láti tọ́jú wọ́n, ṣe ó túmọ̀ sí pé kí ẹlòmíràn máṣe tọ́jú tirẹ̀ ní? Gbogbo ẹ̀yin tí inú ń bi, ẹ lọ gbà fún ẹni ti Ọlọ́run yọ́nú sí."

Bakan naa ni Toyosi ke si awọn obinrin to n pe awọn osere tiata lobinrin ni asẹwo, lati bọ sita wa sọ boya ọkọ to gbe wọn sile lo ja ibale wọn.

Amin iyasọtọ kan

N kò ṣàánú mọ́ fáwọn àgbà òṣèré torí ìrọ́ tẹ pa mọ́ mi

Foluke Daramola

Oríṣun àwòrán, Foluke Daramola

Gbajugbajà òṣèré tíátà Yorùbá, Foluke Daramola tí rọ ará ìlú láti kọ etí ọ̀gbọin sí àhesọ ọ̀rọ̀ kan tó n lọ pe, òun ń fí owó tí àwọn ènìyàn dá fún ètò ẹlẹyinjú àànú tí òun ṣe, se ìtọ́jú ara oùn.

Foluke Daramola ni kàkà bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ owó tí òun ṣe ni òun ń lò láti ṣe ìtọ́jú àwọn arúgbó osere tiata tí òun máa n fún lówó.

Sáájú ni ọkàn nínú àwọn alátẹ̀lé rẹ̀ lórí ayélujára Instagram rẹ, tí kọ ǹkan sí abẹ ọ̀rọ̀ kan tí Foluke fi síta eyi to ni:

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Gẹ́gẹ́ bí nǹkan ti òun rí lórí ayelujara pé " kí òṣèré náà ṣe ǹkan tọ yẹ lórí ọ̀rọ̀ owó náà tí kò bá fẹ́ kú, bákan náà ló tún kọ pé, Foluke já ọkọ ọlọ́kọ gba ni.

Ìdí tí Foluke Daramola fí fèpè bọnu lójú òpó Instagram rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Foluke Daramola

Sùgbọ́n nínú ìdáhùn Foluke Daramola lo ti bẹ̀nu àtẹ lu ọ̀rọ̀ tí ẹni náà sọ tó si ṣẹ́ èpè lé pé lé nítorí pé òun bá òun lórùkọ jẹ́ ni.

Bákan náà ni òṣèré náà tún fi ìdí rẹ́ múlẹ̀ pé, òun kìí gba owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni láti ran ajọ ẹlẹyinjú àǹù tí òn dásílẹ̀ lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bi ẹni náà ṣe sọ bíkò ṣe pé, òógùn ojú òun ni òun ń ná fún wọ́n.

Bákan náà lo ké sí ẹnikẹni tó bá ni ẹri tó dájú kí o gbe wá sí ìtà gbangba kí wọn ye wá sí abẹ́ àkọlé òun láti wá kọ ìkọkúkọ.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Èló gan ni mó n fún àwọn arúgbó yìí gan, 5000, 10000 tí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ kí iná ọlọrun sọ̀kalẹ̀ lé ẹni náà lórí

Fún ìgbà ìkẹyín mó fẹ́ kí àlàyé yìí ye olúkúlùkù " Mi kìí gba owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni láti ṣe iṣẹ́ tí mo yàn layò láti má ràn àwọn arúgbó Nollywood lọ́wọ́.

Owó ara mí ni mo fí n ṣe e, àwọn ti wọn ni mó ni ibi tí mo ti n gba owó, tí wọn sì ni ẹ̀rí, kí wọ́n bọ si gbangba láti wá sọ ọ.

Ìdí tí Foluke Daramola fí fèpè bọnu lójú òpó Instagram rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Foluke Daramola

Bí kò bá sì tí sí ẹri, ẹ yé e wá si ojú òpó instagram mi láti kọ ìkọkukọ, kí ìbínú Ọlọ́run tó rọ̀ lé yín lórí."

Osere tiata naa fikun pe " Ọpọ igba ni wọn ti n sọ ahesọ ọrọ nipa isẹ aanu toun n se, to si ni oun ti oun nifẹ lati se ni isẹ aanu naa fawọn agbaagba osere tiata, ti oun ko si da owo kankan si apo ara oun."

Bakan naa lo sẹ lori iroyin kan to ni awọn olootu ere tiata meji ba oun ni ajọsepọ ni ibudo ere, ki wọn le fun oun ni ipa lati ko ninu ere wọn.

Àkọlé fídíò, Female Car Painter: Èmi ní obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò máa ṣiṣẹ́ akunmọ́tò ní Ibadan

Epe pọ ti Foluke Daramola sẹ, ti a ko le kọ sita , amọ to pa fidio naa rẹ loju opo rẹ, eyi to fi n fi ẹhonu han sawọn eeyan to n pa irọ mọ pe o gba owo lọwọ awọn eeyan kan, ti wọn si tun ni o n se sina pẹlu awọn olootu ere tiata.