Pa Kasumu: Òṣèré tíátà Yorùbá ní àìsàn tó ń bá òun fínra kìí ṣojú lásán

Oríṣun àwòrán, Twitter/Joba Bamiro
Gbajugbaja osẹre tiatia, Kayode Odumosu ti ọpọ mọ si Pa Kasumu ti ke gbajare pe adura awọn eeyan loun nilo bayii nitori aisan to n ṣe oun, ejo lọwọ ninu ni.
Fọnran kan to jade laipẹ yii nibi eto ti Foluke Daramola ṣe lo ṣafihan bi Pa Kasumu ti ri nitori aisan to ti n ba a finra lati ọjọ pipẹ.
Amọ nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Pa Kasumu ni oun ko nilo owo lati ọdọ awọn ololufẹ oun bi ko ṣe adura nitori aisan to n da agọ ara oun laamu ti kọja ọrọ oogun oyinbo lilo.
- 'Penis Fish", ẹ̀ja tuntun tó rí bí ǹkan ọmọkùnrin lùwẹ̀ jáde lórí òkun
- Kò sí ọkùnrin tí yóò fún obìnrin tó halẹ̀ bíi tèmi lówó - Lizzy Anjorin
- Ẹ́ wo ojú àwọn òṣèré tíátà tó péjú sí Ibadan fún ìpàdé ọlọ́dọọdún
- Saheed Balogun sìnkú ìyá rẹ̀, Ogogo ní ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù!
- Èmi àti Adewale Ayuba ò ja, Ọlọ́run ló fún mi lóhùn t'èmi - Ajebori Onifuji
- Táyà ọkọ̀ agbépo tó fọ́ fa ìjàmbá ọ̀kọ̀ l'Ékò, èèyàn kan farapa
- Boris Johnson àti ẹgbẹ́ rẹ̀ wọlé ìbò, Trump àtàwọn ààrẹ míì kíi kú oríire
- Ọdun ń lọ sópin, ariwo 'ń sọ̀ ní ilé ńlá l'Abuja
- Ẹjọ́ Sowore bọ́ sọnù lọ́wọ́ àjọ DSS
Pa Kasumu ni oun wa ni ipagọ adura ile ijọsin kan nibi t'oun ti n gbadura fun iwosan agọ ara oun, o ni oun si maa wa nibẹ ti eto naa yoo fi pari.
Ọgbẹni Odumosu to ti n ṣaisan lati bi ọdun mẹwaa sẹyin ṣalaye pe ijọ RCCG ni ṣọọṣi akọkọ ti oun yoo lọ fun ẹbẹ adura lati igba ti aisan naa bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Funso Dove
O ni ṣọọṣi ti oun n lọ ni Sabo, Yaba naa n gbadura fun oun.
Pa Kasuma tun fi kun ọrọ rẹ pe irọ ni iroyin tawọn eeyan kan n gbe kiri pe oun ti ni ipenija pẹlu oju oun.
O ṣalaye pe awọn dokita sọ f'oun pe oun ni aarun rọpa rọsẹ eleyi to ṣakoba fun apa kan ara oun, ti o si tun ba oju oun.
O ni iyawo oun atawọn ọmọ ni wọn n ṣe itọju oun lati igba ti aisan yii ti bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Ridwanullah
Ọkan lara awọn ọmọkunrin Pa Kasumu, Bode Odumosu naa sọ pe adura ni baba oun nilo bayii pẹlu ipo to wa.
Lọdun 2017 ni iroyin kan jade pe aisan to n ṣe Pa Kasumu tun n le sii lẹyin to pada si Naijiria lati orilẹede India nibi to ti lọ gba itọju.












