Professor Elusiyan: Ọ̀jọ̀gbọ́n Jerome ré s'álákeji lójú ìbọn àwọn afurasí agbébọn

Oríṣun àwòrán, Babajide Adeolu Adewale/Facebook
Awọn afurasi agbebọn ti gbẹmi alaga igbimọ agbaninimọran lori eto ilera ni ile iwosan Fasiti Obafemi Awolowo, Ile Ife, ipinlẹ Osun, Ọjọgbọn Jerome Elusiyan.
Iroyin taa gbọ ni pe oloogbe naa n dari pada lọ sile lati ile iwe fasiti Ambrose Ali (AAU) nibi to ti lọ ṣamojuto idanwo awọn akẹkọọ ẹ̀ka iṣegun oyinbo to n ri si itọju awọn ọmọde.
Fasiti Obafemi Awolowo kede ipapoda oloogbe Ọjọgbọn loju opo Twitter wọn pẹlu ọkan wuwo.
Iroyin tun sọ pe awọn agbebọn da a lọna lopopona Benin si Auchi laarin ilu Iruekon ati Ekhor ti wọn si ṣina ibọn bolẹ si ọkọ rẹ ko tilẹ to lee sọ pe oun fẹ duro.
Wọn ni loju ṣe ni oloogbe faye silẹ ti awakọ rẹ si fara pa yanayana latari awọn ọta ibọn ti wọn yin lu wọn.
Ẹwẹ, ẹka ẹgbẹ awọn onimọ iṣegun oyinbo ti ipinlẹ Edo banujẹ gidi gan an si iṣẹlẹ ibanujẹ yii.
Ninu ọrọ ti alaga ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Edo, Dokita Valentine Omoife fọwọ si, wọn bu ẹnu atẹ lu iṣoro aabo atawọn iṣẹlẹ aidaa miiran tawọn oniṣẹ ibi n ṣe lorilẹ-ede Naijiria.
Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn onimọ iṣegun oyinbo ni ipinlẹ naa ni awọn ti kọ́ lẹta ranṣẹ si Gomina ati Kọmiṣọnna Ọlọpaa ipinlẹ Edo ti kọ iwe ranṣẹ si ile iṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ lati ri aridaju aabo fun ẹmi awọn ọmọ ẹgbẹ wọn to ku.















