Nigeria Presidency: Kí ló ń fa wàhálà ojojúmọ́ ní ilé Ààrẹ l'Abuja

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident
Fun awọn asiko diẹ, alaafia jọba ni ile aarẹ nilu Abuja nitori ọpọ awuyewuye ti o maa n waye nibẹ ni ko dede waye mọ. Nigba naa ọpọ woye pe boya tori idibo to waye ni.
Amọṣa, o dabi ẹni pe bi ọdun ṣe n lọ sopin bayii ni ariwo tuntun n sọ ni ile nla l'Abuja.
- Makinde kò gbé àjọ ìwà ìbàjẹ́ kalẹ̀ torí ìfẹ́ aráàlú, ó ń fẹjú mọ́ alátakò ni - Ọmọ ẹgbẹ́ APC
- Ẹjọ́ Sowore bọ́ sọnù lọ́wọ́ àjọ DSS
- Àjọ̀dún àṣà nípínlẹ̀ Ekiti, EKIFEST pinminrin!
- Ìlé ẹjọ́ rọ Obalufe ti Ile Ife lóyè, wọ́n pàṣẹ́ fún Ọọ̀ni Adeyeye
- Àwọn èsì yín tó ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ìyanṣẹ́lódì ilẹeṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná rèé
Ni ọjọ kẹtala oṣu kẹwaa ọdun 2019 ni iyawo aarẹ Buhari de si orilẹede Naijiria lẹyin to ti lo ọpọ ọjọ loke okun. Laarin asiko yii ni iroyin iyawo tuntun fun aarẹ jade. 'Kìí ṣe ojúṣe mi láti sọ bóyá òótọ́ ni Buhari fẹ́ gbéyàwó tàbí irọ́'
Rugudu ọrọ yii ṣẹṣẹ fẹ maa dawọ duro ni aya aarẹ, Aisha Buhari de ti o si tun ju akaṣu ọrọ silẹ lori bi ọmọ baba ọkọ rẹ, Daura, iyẹn Fatima ṣe n fi oun ṣe yẹyẹ lori igbesẹ ati fidi aṣẹ ti aarẹ pa pe ki oun atawọn ẹbi rẹ kuro ni ọkan ninu awọn ile to wa ni ile aarẹ fun Yusuf ọmọ ọkunrin aarẹ lati gbe. "Ọmọ Daura ti tàpá sí òfin ààbò Nàíjíríà, ó sì yẹ kí Buhari le è to ilé rẹ̀"

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident
Ariwo eyii naa pọ.
Ko pẹ lẹyin eyi ni aya aarẹ ba tun pariwo sita pe awọn minisita atawọn gomina ko ṣe ojuṣe wọn fun alaafia araalu. Nibi eto kan eyi ti igbakeji aarẹ funrarẹ wa lo ti sọ eyi.

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, lasiko ti gbogbo eyi ti n ṣẹlẹ ni ina iroyin kan naa n ja ranyinranyin pe awọn eeyan kan n gbimọ pọ lati yọ igbakeji aarẹ nipo. Oniruuru ọrọ lawọn eeyan sọ nigba naa.
Ariwo to n waye yii ni ile aarẹ ko fi ọkan ọpọ balẹ nitori afihan pe nnkan o rọgbọ nile aarẹ ni.
Laipẹ yii ni ajọ DSS ya bo kootu kan nilu Abuja ti wọn si da jinijini bolẹ. Nigba ti ileeṣẹ aarẹ yoo sọrọ, o ni ko soun to bajẹ ninu ohun to ṣẹlẹ naa nitori ojuṣe ajọ DSS lo n ṣe. Amọṣa, Yẹmi Osinbajo to jẹ igbakeji larinlọọdu ni ile aarẹ ni tirẹ ṣe akawe rẹ gẹgẹ bii idojuti nla gbaa eleyi to ni o mu ki oun maa lee gba ami ẹyẹ kan ti wọn fẹ fun oun.

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident
Eyi mu ki ọpọ maa beere pe, ki gan lo n ṣẹlẹ debi pe ohun igbakeji baba onile ko ṣọkan pẹlu ileeṣẹ aarẹ.
Iyanu ọrọ yii ko tii balẹ lara awọn ọmọ orilẹede Naijiria nigba ti iyawo aarẹ ni tirẹ ba tun pariwo sita pe amugbalẹgbẹ fun aarẹ lori ọrọ iroyin Garba Sheu tí gbàbọde, Aisha Buhari figbe ta fun ọkọ oun o ati pe iṣẹ ti wọn ko ran an lo n jẹ kaakiri.
Ibeere nla wa ni ọrọ naa n ko jade fun ọpọ pe, ki lo ṣe iṣọkan ni ile aarẹ labẹ aarẹ Buhari?












