Aisha Buhari: Kìí ṣe ojúṣe mi láti sọ bóyá òótọ́ ni Buhari fẹ́ gbéyàwó

Iyawo aarẹ, Aisha Buhari

Oríṣun àwòrán, AISHA BUHARI/TWITTER

Iyawo aarẹ orileede Naijiria, Aisha Buhari ti ni kii ṣe ojuṣe oun lati da awn eeyan lohun boya ootọ ni ọkọ oun fẹ gbeyawo tuntun.

O sọ fun BBC pe awọn mejeji tọrọ naa kan lo ni ojuṣe lati da awọn eeyan lohun ibeere wọn. "Oun (Buhari) ni awuyewuye sọ pe o fẹ fẹyawo kii ṣe Aisha Buhari".

Iyawo aarẹ ni "awọn lo yẹ ko jade wa jẹ ki afẹfẹ fẹ kaye le mọ ohun to n ṣẹlẹ, ṣugbọn ẹni ti wọn ni o fẹ fẹ gan ko reti pe ko ni ṣẹlẹ tori ko jade sita lati wa sọ pe ir ni ayafi igba ti ọjọ tawọn eeyan n sọ kọja".

Aisha Buhari bu ẹnu atẹ lu awuyewuye to n sọ wi pe o fi ọkọ rẹ, aarẹ Buhari silẹ lọ si oke okun tori ko fẹ lọwọ ninu ipinu rẹ lati fẹ iyawo keji.

Iyawo aaarẹ to ni ọrọ ilera ni oun ba lọ si ọdọ awn dokita ni ilu London laarin oṣu meji ti oun ko fi si nilu spe nigba ti oun pada de, oun ko mọ ohunkohun to n lọ lori ayelujara nipa ero atiṣegbeyawo kankan.

Lọsẹ to kọja ni iroyin ofege kan tan kalẹ pe aarẹ Buhari fẹ fẹ minisita rẹ̀ kan, Sadiya Umar Farouk niyawo lọjọ Ẹtì ṣugbọn olubaṣiṣẹ Aisha Buhari kan sọ fun BBC pe kii ṣe ootọ.

Àkọlé fídíò, Kayode Abiara: Ọmọ Nàíjíríà, ẹ má ba ọkàn jẹ́ lórí ààbò tó mẹ́hẹ, ewu ìgbà ìkẹyìn ló jẹ́