EKIFEST: kí làwọn ohun tó fakọyọ níbi àjọ̀dún àṣà nípínlẹ̀ Ekiti, EKIFEST tọdún 2019

Àkọlé fídíò, Ijo awọn ẹgbẹ alaṣa ni Ekiti

Ipinlẹ Ekiti ni aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba paapaa awọn to nii ṣe pẹlu awọn eeyan ilẹ Ekiti ko ni parun. Idi niyi ti ayẹyẹ ajọdun aṣa fi waye nibẹ.

Ayẹyẹ ajọdun aṣa ipinlẹ Ekiti ti wọn da pe ni EKIFEST n waye lọwọlọwọ bayii ni ilu Ado Ekiti tii ṣe olu ilu Ipìnlẹ Ekiti. Awọn ẹgbẹjẹgbẹ ati ọgba ni wọn ti peju sibẹ lati Ọjọru ti ayẹyẹ naa ti bẹrẹ.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Yorùbá foríkorí gbé ìwé tó lè sọ ẹ̀yà ara yín lédè Yorùbá.

Lara awọn manigbagbe ohun to waye lasiko iṣide ayẹyẹ ajọdun aṣa naa lọjọru ni ayẹyẹ afihan awọn ẹgbẹ aṣa gbogbo lati gbogbo ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa nibi ayẹyẹ naa. Bakan naa lawọn oṣere tiata Yoruba ati ede oyinbo ko gbẹyin nibẹ.

Awọn ẹgbẹ aṣa kan

Oríṣun àwòrán, Sunkanmi

Ẹwẹ awọn ẹgbẹ gbogbo lati awọn ẹya ede miran pẹlu wa nibẹ ti awọn olorin si n fi alujo to ba igba mu da awọn to wa nibẹ laraya.

Awọn ẹgbẹ agbaṣaga

Ninu ọrọ rẹ, Gomina Kayọde Fayẹmi to ṣide ajọdun ọhun tẹnumọ ipinnu iṣejọba rẹ lati tubọ ya owo sọts fun igbelekeẹka aṣa ati iṣe fun idagbasoke ọrọ aje awọn eeyan ipinlẹ Ekiti.

Ni ọjọ Ẹti ni aṣekagba ajọdun naa yoo balẹ ni ilu Ado Ekiti.

Àkọlé fídíò, Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde