New Muhammadu Buhari: Ọkùnrin kan ní Kano ṣ'ayẹyẹ ìsọmọlórúkọ lẹ́yìn tó yí orúkọ padà sí Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Naijassador
Bo ba ti wu ni laa ti ṣe igbagbọ ẹni.
Ọkunrin kan niluu Kano lo yii orukọ ara rẹ pada si orukọ aarẹ ọrilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari.
Ọkunrin naa to jẹ ẹni ọdun mejidinlogoji tilẹ ṣe ayẹyẹ ikomọjade ọtun lati dawọọ idunnu yi yi orukọ rẹ si Muhammadu Buhari.
Oriṣiiriṣii aworan lati ibi ayẹyẹ isọlmọlorukọ ni ọpọlọpọ eeyan ti gbe soju opo ayelujara.
Iroyin to tẹ wa lọwọ fidi rẹ mulẹ pe lopopona to lọ si ọgba iko ẹranko si ni ayẹyẹ naa ti waye ni Zoo road ni olu ilu Kano.
Okunrin naa fiwe pe Aarẹ Buhari ati gomina Abdulahi Ganduje sibi ayẹyẹ isọmọlorukọ naa.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Abdulla

Oríṣun àwòrán, Twitter/Informationng
Koda ọkunrin naa pa ẹran agbo lati fi dawọọ isọlmọlorukọ ara rẹ gẹgẹ ilana eṣin musulumi.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Officialpetestack
Eleyi le jẹ iyalẹnu fun ọpọ eeyan, paapaa lasiko ti awọn eniyan n sọrọ lori aibọwọ fun ofin ile ẹjọ ti wọn ni pe o wọpọ lasiko aarẹ Buhari yii.
Bẹẹ, awọn eniyan ilu Kano ni ko ri bẹẹ lọdọ ti wọn nitori pe awọn ara ipinlẹ naa tu yaaya tu yaaya dibo fun Aarẹ Buhari ninu idibo gbogbogbo ọdun 2015 ati 2019.













