Lagos murder: Ọwọ́ ọlapàá tẹ afurasí òṣìṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná tó gún tọkọ taya lọ́bẹ ní Ikoyi

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bernadett Kurucz
Ọwọ ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ti tẹ afurasi meji, Ade Akanbi ati Olamide Adegoke ti wọn fẹsun kan pe wọn gun tọkọ taya lọbe nile wọn ni Ikoyi niluu Eko lọjọ Aiku.
Agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Bala Elkana ṣalaye pe awọn afurasi yii gun ọkunrin kan, Gildas Tohouo to jẹ oludari ile iṣẹ ọja kiko wọle lori omi ati iyawo rẹ lọbẹ, eleyi to mu ki iyawo rẹ dero ọrun.
Ile iṣẹ ọlọpaa ni nibi aago mọkanla aabọ lalẹ tawọn alejo ti lọọle tan, ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.
Agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa, Bala Elkana ni awọn ile iṣẹ mọnamọna lo muna lọ, ni oṣiṣẹ ina mọnamọna kan, Olamide Adegoke wa lati ṣe iranwọn fun wọn lori titan ati titun ẹrọ amunawa wọn ṣe.
Kete ti wọn ṣilẹkun fun oṣiṣẹ mọnamọna naa ati ẹni to tẹ le e lo bẹrẹ si ni gun wọn lọbẹ lati le ja wọn lole.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Gildas Tohouo
Olamide jẹwọ fawọn ọlọpaa pe oun ti beere owo lọwọ ọkunrin naa ri ṣugbọn o kọ lati fun oun.
Ile iṣẹ ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe ọmọ orilẹ-ede Cameroon ni Ọgbẹni Tohouo nigba ti iyawo rẹ si jẹ ọmọ ilẹ Hungary.
Awọn agbofinro sọ pe awọn afurasi mejeeji ti jẹwọ fawọn ọlọpaa pe awọn lawọn ṣiṣẹ laabi ọhun.
Koda, Ọgbẹni Bala Elkana ni ile iṣẹ ọlọpaa ti ri ọbẹ ti wọn fi ṣiṣẹ laabi ọhun gba, bakan naa ni wọn gba kaadi igbowo (ATM card) ati pọọsi kan ti owo wa ninu rẹ ti wọn ji nile awọn tọkọ taya naa.












