Kílódé tí ìjọba Nàíjíríà kò fòpin sí lílo ike rọ́bà lẹ́ẹ̀kan?

ROBA

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àjọ tó ń rísí ọ̀rọ̀ ojú ọ́jọ́ ti ní Naijiria sí ń lo ike nígbàkúgbà lẹ́ẹ̀kan sọsọ lẹ́yìn tí àwọn orílẹ̀èdè míràn ti fí òpin si.

Ajọ to n risi ọrọ oju ọjọ ti ni ọpọlọpọ ipenija lo wa ninu ki orilẹ-ede kọ lati maa lo ike nigba gbogbo lati daabo bo ayika.

Atâyi Babs to jẹ adari Ajọ 'Climate and Sustainable Development Network' ti ni ida aadọrun eniyan lo n lo ike rọba lai si pe wọn maa tun un lo nigba miran lati dawọ ẹkun omi duro lagbaye.

Ninu ọrọ rẹ, Babs ni iwadii lati Ajọ Ocean Conservancy f han pe ike rọba yoo pọ ju ẹja lọ ninu okun ni ọdun 2050.

Àkọlé fídíò, Segalink:ìkùnsínú pọ̀ láàrin àwọn agbófinró bẹ́ẹ̀ wọn kò ni agbẹnusọ

O ni awọn n ra ike rọba miliọnu kan lagbaye ni isẹju aaya kan, ti awọn si n lo to triliọnu marun un ike rọba lọdọọdun.

ROBA

Oríṣun àwòrán, Barcroft Media

Àkọlé àwòrán, Ta ike rọba ki o di olowo

Atâyi Babs fi kun un wi pe ijọba apapọ Naijiria ni isẹ pupọ lati se, lati ri i wi pe opin de ba lilo ike rọba ni awọn igberiko, ẹsẹ kuku ati awọn ilu nla nla.

ROBA

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lilo ike rọb lẹẹkan n ṣakoba fun ayipada oju ọjọ ni agbaye ni
Àkọlé fídíò, Segalink:ìkùnsínú pọ̀ láàrin àwọn agbófinró bẹ́ẹ̀ wọn kò ni agbẹnusọ

Adari Ajọ 'Climate and Sustainable Development Network' ni ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede ni ilẹ Afirika bii Côte d'Ivoire, Cameroon, Mauritania, Tunisia, Kenya, Uganda, Rwanda, Tanzania, Morocco ati South Africa lo ti gba lati f'opin si lilo ike rọba ati ipenija rẹ.

Àkọlé fídíò, Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀
Àkọlé fídíò, JAMB 2019: A ó fagi lé ìdànwò ẹni tó bá ṣe aṣemáṣe