Lagos Killings: Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ṣèkìlọ̀ pàtàkì fún àwọn ọlọ́pàá

Lataari ipaniyan to n waye ni lemolemo ni ipinlẹ Eko, ọga agba ọlọpaa ṣabẹwo ojiji.
Oga agba awọn ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria, Mohammed Adamu ko fi ọkan pe meji, to ti tẹ'kọ leti de ilu Eko lati kilọ fawọn agbofinro.
Ọga agba Mohammed bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu isẹlẹ yii, paapaa awọn to n wa lati ọwọ awọn ọlọpaa, o ni eyi ko jẹ itẹwọ gba rara.
Nigba to n ba awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa sọrọ ni ile iwe awọn ọlọpaa to wa ni Ikeja l'Eko, Mohammed ni bii ipari ọdun lo yẹ ki oun yọju si Eko ṣugbọn oun ni lati wa ni akoko yii nitori bi ipaniyan lai bofin mu ṣe n peleke sii.
Ẹwẹ, ọga agba ọlapaa fa gbogbo ọlọpaa leti o si sọ awọn koko ọ̀rọ̀ pataki kan ati awọn ikilọ pataki to fi mọ ijiya fun ẹnikẹni ninu awọn ọlọpaa to ba pa eniyan lai ba ofin mu.
- Awọn alaṣẹ ajọ ọlọpaa ko ni faaye gba aṣilo agbara rara.
- Ẹni to ba dan an wo, yoo de ile ẹjọ fun ẹsun ipaniyan tabi oniruuru ẹsun ti yoo si da lori ipele ẹṣẹ rẹ.
- Bakan naa, ọlọpaa to n ṣabojuto ọlọpaa to ba daran to fi mọ oludari agbegbe (Area Commander), oludari ẹkun (Divisional Police Officer / Sectional Head) naa yoo fori ko ẹjọ lori aimojuto to peye wọn yoo si fi jofin.
- Fun akoko melo kan, dipo lilo ibọn, awọn ohun elo imọ ẹrọ bii ẹda ibọn mii ti oloyinbo n pe ni "electro-muscular disruption technology, Taser tabi Stun gun". Ohun ni wọn yoo maa fi ṣe ayẹwo kiri.
- Nibayii, a o bẹrẹ si ni ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹgbẹ tabi ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, awọn ajọ agbaye, ajọ to n ri si idagbasoke ati awọn ẹgbẹ araalu.
- Ọpọlọpọ idari latọdọ awọn alaṣẹ ni yoo maa wa lati ṣe ilanilọyẹ ati idanilẹkọọ to ni ṣe pẹlu ẹtọ ọmọniyan fun awọn ọlọpaa.














