Tiger Woods ló borí ní ami ẹ̀yẹ Masters ti 2019 ní Augusta

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn Yoruba ni, bi ẹsin ba da ni, a maa n tun gùn ni.
Ohun lo difa fun bi gbajugbaja agbabọọlu gọọfu, Tiger Woods ṣe pada wa di ọba ere bọọlu yii lẹyin ọdun mọkanla ti ọpọ eniyan ni agbaye ro pe aye rẹ ti bajẹ patapata.
Woods pari lọna aramọda lati gba ife ẹyẹ Masters ti ọdun 2019.
Ife ẹyẹ yii ni ikarun un iru rẹ ti yoo gba. O gba akọkọ ni ọdun 1997 nigba to wa ni ọmọ ọdun mọkanlelogun pere.
O ti wa di igba marundinlogun ọtọọtọ ti yoo gba ife ẹyẹ gboogi ni gọọfu bayii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fun bii ọdun mọkanla ni Woods n tiraka lati gbe'gba oroke ninu idije gọọfu lẹyin ti wọn ti fi ẹsun aṣemaṣe agbere kan an, eyi to tu idile rẹ ka, to si mu ijakulẹ ba a ninu gbogbo oun to da'wọle.
Ṣe ni Woods, akọni ọmọ ọdun mẹtalelogoji naa fi igbe ta nigba to jawe olu bori. O ni oun ko lero pe oun yoo jawe olubori rara.
Ki ẹnikẹni ma ṣe ro ara rẹ pin.














