Bi ìyàwọ mi ṣe n jábọ́ sí gọ́tà ló jẹ́ kí n kọ́kọ́ fura pé kò ríran mọ́- ọkọ Dorcas
Tete ṣe ayẹwo oju rẹ ko too pẹ ju- Ọjọgbọn Adeọla Onakoya
Aisan Adakẹfọju-ẹni ti awọn oloyinbo n pe ni Glaucoma ni ọpọ awọn eniyan Naijiria ko ka kun pupọ nitori pe kii mu ariwo dani.
Ọpọ awọn eniyan ni kii tete fura pe o ti n ba awọn ja ni eyi to maa n gba oju lọ to ba ti pẹ lara.
Arabinrin Damola Funmilola Dorcas ṣalaye lori irir rẹ ṣaaju ko to ni arun yii ati bi o ṣe wa gba oju lọ lọwọ rẹ.
Ọgbẹni Omogbolahan Damola to jẹ ọkọ Dorcas ṣalaye fun BBC bi ọrọ ifọju iyawo rẹ ṣe bẹrẹ ko to
Bakan naa ni BBC tun kan si oniṣegun oyinbo to jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa itọju oju ṣalaye nipa ayẹwo nipa adakẹ-fọju-ẹni Glaucoma.
Onimọ iṣegun Adeola to jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa ọrọ oju ni ile iwosan ijọba ni Idi Araba mẹnuba igbesẹ to yẹ ni gbigbe fun itọju oju.
Dorcas sọrọ lori bi aisan yii ṣe gba oju lọwọ oun ti oun ko fi le ṣiṣẹ olukọ mọ.