Lagos Cane Village: Lórí iṣẹ́ ikàn yìí, a ti kọ́ ilé, ọmọ ti lọ ilé ìwé
Abule ikan yii jẹ ọkan lara awọn ibudo ti wọn ti n fi ikan ṣe oriṣiriṣi nkan amulo oun si lo tobi ju laarin awọn iru ẹ ni ipinlẹ Eko.
O ti di ilu ti awọn oniṣowo n gbe ti wọn ti n sun ti wọn ti n ji, jẹun, ṣiṣẹ, ran ọmọ lọ ile iwe ati ọpọlọpọ ohun teeyan n ṣe lati gbe aye.
Awọn oniṣowo to wa nibẹ ṣalaye iwuri to wa ninu iṣẹ ikan hihun ati awọn ipenija to jẹ ko ṣee mani.