Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí Goodluck Jonathan ní òun ó ni ọrọ̀ kankan nílẹ̀ Òkèrè

Oríṣun àwòrán, PHILIP OJISUA
Aarẹ Naijiria tẹlẹri Goodluck Jonathan ti ni, ati ile ati ileeṣẹ to fi mọ akoto ikowopamọsi nilẹ okere, ohun ko nikankan ninu wọn.
Ọrọ rẹ yi jẹ esi to fọ ni idahun si iroyin kan to gbode pe awọn agbẹjọro ijọba apapọ ti forukọ rẹ sinu awọn to n gbẹjọ ajẹbanu niwaju ile ẹjọ kan nilu London pe o gba abẹtẹlẹ.
Ninu atẹjade kan ti a ri lati ọwọ oluranlọwọ rẹ lori ọrọ iroyin,Ikechukwu Eze,Aarẹ Jonathan ni awọn ko ṣẹṣẹ ma gbo iru irọ bẹ.
O ni "Aarẹ tẹlẹri ko bere tabi gba abẹtẹlẹ...ko si si ohun to jọ bẹ''
"Ọrọ ti wọn n sọ yi ti waye saaju ki Jonathan to d'ori alefa o ṣi yi tẹsiwaju lẹyin to kuro.Ọmọ ọdun mọkanlelọgọta ni Aarẹ Jonathan ko si fi igba kankan kowopamọ si ilẹ okere tabi ko ni ile lẹyin odi''
Ijọba apapọ Naijiria ni aiṣedede waye nipa bi awọn ile iṣẹ ipọnpo Eni ati Shell ṣe gba agbaṣe iṣẹ ni Naijiria ti wn si gbe wọn lọ si ile ẹjọ lati san owo itanran biliọnu dọla 3.5
Iroyin ta gbọ ni pe awọn ọga kan ni ile iṣẹ Shell to n wa epo rọbi ni Naijiria fun awọn oṣiṣẹ ijọba kan ni abẹtẹlẹ lati le gba aye ipọnpo OPL 245 lọdun 2011.
Ile ẹjọ kan ni orileede Faranse dajọ pe minisita ọrọ epo rọbi tẹlẹri Dan Etete jẹbi magomago ti o si fi owo eru ra ọkọ oju omi ati ile nla kan.
Bi ọrọ ti ṣe ri bayi, Aarẹ Jonathan ko jẹjọ kankan lori ọrọ naa.












