Ẹgbẹ ajafẹtọẹni nfẹ iwadi tuntun lori ifọnkalẹ epo rọbi

Ina sẹyọ nibudo ipọnpo kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọ igba ni wahala ibajẹ ayika ti sẹlẹ lẹkun Niger Delta nitori aibikita awọn ileesẹ apọnpo nibẹ

Ajọ to n tọpinpin ẹtọ ọmọniyan lagbaye, Amnesty international (AI) ti ke si awọn alasẹ lorilẹede Naijiria lati tun iwe iwadi si lori isẹlẹ ifọnkalẹ epo rọbi to waye lẹkun Niger delta.

AI ni Naijiria gbọdọ fidi ofin mulẹ lẹka epo rọbi lati dẹkun aibikita awọn ileesẹ apọnpo bii Shell ati Eni.

Ninu abajade iwadi rẹ kan to gbe jade lopin ọsẹ, ajọ naa n fi ẹsun kan awọn ileesẹ apọnpo rọbi Shell ati Eni pe aibikita wọn lo sokunfa bi epo rọbi se n fọnka si ayika lẹkun naa eleyi to ti di wahala ibajẹ ayika ati agbegbe nibẹ.

Agbegbe kan ti wahala ifọnka epo rọbi ti sọsẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọkẹ aimọye ẹmi, dukia ati ohun amusajejẹun awọn eeyan Niger Delta lo ti ba wahala ifọnka epo rọbi lọ

Ẹsun ti ajọ Amnesty International fi kan awọn ileesẹ ipọnpo mejeeji yii ko kere rara.

Tawọn alasẹ lorilẹede Naijiria ba lee gba abajade iwadi naa wọle, eyi yoo fun ọpọ awọn ileto ati ilu to ti fara kaasa ọwọja wahala ifọnka epo rọbi lanfaani lati gbe awọn ileesẹ mejeeji lọ sileẹjọ fun biba agbegbe wọn jẹ lai san owo gba-maa binu.

Gẹgẹbii ajọ Amnesty International se sọ, iroyin eke ni ileesẹ ipọnpo Shell ati Eni n gbe kaakiri lori ohun to n sokunfa ifọnka epo rọbi lẹkun Niger Delta.

Eefin ati ina n ru jade ni ibudo ipọnpo kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ọdọ agbebọn lẹkun naa ti kọkọ bẹrẹ ikọlu awọn ibudo ipọnpo lẹkun naa ki alaafia ranpẹ to jọba

Ajọ naa ni ko si ootọ ninu ariwo ti ileesẹ ipọnpo Shell ati Eni n pa pe gbogbo ipa awọn lawọn n sa lati rii wi pe epo rọbi ko fọnka kiri lagbegbe naa ati pe fun ọpọlọpọ osu ni wọn kii fi da si ipe lori ifọnka epo rọbi lagbegbe naa.

Ajọ naa tun salaye apẹẹrẹ kan ninu eyi to gba ileesẹ ENI ni ojilenirinwo o din mẹwa ọjọ lati gbe igbesẹ dipo wakati mẹrinlelogun ti ofin orilẹede Naijiria la kalẹ.

Ajọ Amnesty international ni awọn yoo gbe abọ iwadi awọn kalẹ niwaju ijọba orilẹede Naijiria pẹlu ipe lati mu ki wọn tubọ tẹnpẹlẹ mọ ifidimulẹ awọn ofin gbogbo to de ẹka epo rọbi.