Hot mic moment: Àwọn ìlúmọ̀ọ́ká olórí orílẹ́-èdè tó sọ̀rọ̀ fẹnu kọ pẹ̀lú ẹ̀rọ gbohùngbohùn rèé

George W Bush and Tony Blair

Oríṣun àwòrán, Press Association

Àkọlé àwòrán, Àwọn ìlúmọ̀ọ́ká olórí orílẹ́-èdè tó sọ̀rọ̀ fẹnu kọ pẹ̀lú ẹ̀rọ gbohùngbohùn rèé

Aṣiwi ko to aṣisọ, iyẹn lo difa fun awọn aarẹ orilẹ-ede kan lagbaye ti wọn ṣi ọrọ sọ pẹlu gbohungbohun.

Ohun to wọ pọ lagbo oṣelu ni pe ifura lagba oogun, awọn oloṣelu ko gbọdọ maa ro pe gbohungbohun ko si ni titan nigba gbogbo.

Ṣugbọn iyanlẹnu lo jẹ pe ọpọ awọn olori orilẹ-ede lo maa n saaba gbagbe eleyi.

Awọn aṣisọ ọrọ lati ẹnu awọn ilumọọka oloṣelu lagbaaye kan ti fi abuku nla kan wọn.

Lọsẹ yii ni olootu ijọba orilẹ-ede Canada, Justin Trudeau da bi ẹni pe o n fi Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ṣe yẹyẹ nibi ipade NATO.

Awọn aṣisọ manigbagbe lati ẹnu awọn olori orilẹ-ede marun un ree:

1. Ronald Reagan: 'A o bẹrẹ si ni ju ado oloro ni iṣẹju marun un' (1984)

Aarẹ ilẹ Amẹrika nigba kan ri, Ronald Reagan sọrọ fẹnu kọ nigba ogun 'Cold War' laarin orilẹ-ede Amẹrika ati orilẹ-ede Soviet Union tẹlẹ.

Nigba ti wọn n ṣe ayẹwo gbohungbohun lọwọ ni Aarẹ Reagan ṣeesi sọrọ pe,:

''ẹyin eeyan Amẹrika, inu mi dun lati sọ fun un yin pe mo ti buwọ lu ofin to de Russia laelae, a o bẹrẹ si ni maa ju ado oloro laarin iṣẹju marun un.

Ronald Reagan

2. Jacques Chirac ko fẹran ounjẹ ilẹ Gẹeṣi tabi Finland (2005)

Aarẹ ilẹ Faranse tẹlẹ ri, Jacques Chirac sọrọ to da rugudu silẹ nigba to rinrin ajo lọ si orilẹ-ede Russia.

Aarẹ Chirac ro pe gbohungbohun to wa lọwọ oun ko si ni titan nigba to bẹrẹ si ni sọrọ pe ''awọn eeyan ilẹ Gẹeṣi ko ṣee gbẹkẹle papaa julọ pẹlu bi wọn ko ti ṣe mọ ounjẹ se.

Chirac ni lẹyin ilẹ Gẹeṣi, orilẹ-ede Finland lo tun buru jai pẹlu ounjẹ sise.

Ọrọ naa di aawọ laarin ilẹ Gẹẹsi ati orilẹ-ede Faranse nigba naa.

Jacques Chirac

3. 'Yo Blair!' (2006)

Ninu ipade G8 niluu St Petersburg lorilẹ-ede Russia ni aarẹ ilẹ Amẹrika tẹlẹ ri, George W. Bush ti sọ pe 'Yo Blair!' nigba to ki olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Tony Blair.

Awọn mejeeji ko mọ pe awọn akọroyin n gbọ ohun ti wọn n sọ nigba ti wọn n ki ara wọn.

Awọn alatako Blair ati Bush fi ọrọ naa ṣe yẹyẹ lagbo oṣelu.

George W Bush and Tony Blair

Oríṣun àwòrán, Press Association

Àkọlé àwòrán, Àwọn ìlúmọ̀ọ́ká olórí orílẹ́-èdè tó sọ̀rọ̀ fẹnu kọ pẹ̀lú ẹ̀rọ gbohùngbohùn rèé

4. Gordon Brown's 'alaṣeju obinrin' (2010)

Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi tẹlẹ, Gordon Brown lo pe obinrin kan ni alaṣeju nibi to ti n bawọn eeyan sọrọ ni Rochdale.

Ọgbẹni Brown pada sinu ọkọ rẹ lai mọ pe gbohungbohun si wa lara rẹ, nibẹ ni o ti n ba ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ rẹ sọrọ.

Àkọlé fídíò, Brown: "I apologise if I've said anything that has been hurtful"

Nibẹ lo ti sọrọ pe alaṣeju l'obinrin, Gillian Duffy to beere ibeere lọwọ rẹ.

Amọ, Brown pada tọrọ aforijin lọwọ obinrin naa.

5. 'Ọrọ rẹ ti su mi'- Aṣiṣẹ Obama ati Sarkozy

Awọn akọroyin ni wọn gbọ nigba ti aarẹ ilẹ Faranse nigba kan ri, Nicolas Sarkozy n sọ fun akẹgbẹ rẹ lati Amẹrika, Barack Obama nibi ipade G20 lorilẹ-ede Faranse.

Ọgbẹni Sarkozy lo n sọ fun Obama pe ọrọ olootu ilẹ Israel, Benjamin Netanyahu ti su oun.

Obama fesi pe 'opurọ ni Netanyahu, ọrọ rẹ gan an le mu eeyan ṣe aisan, ohun ti mo n la kọja lojoojumọ niyẹn.''

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Journalist Dan Israel, who broke the story: ''They weren't supposed to hear it, there was a mistake''

Aṣiri ọrọ yoo to tu sita ṣakoba fun ibaṣepọ to wa laarin ilẹ Israel ati ilẹ Faranse pẹlu orilẹ-ede Amẹrika.

Àkọlé fídíò, UI graduation: Fasiti Ibadan ló fún mi ni ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tí mo fi kàwé síi- Habibat