Border closure: Wo àwọn ọ̀nà àràméèrírí táwọn èèyàn fi ń kó ìrẹsì wọ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Others
Ni oṣu kẹjọ ọdun 2019 ni ij.sba apapọ kede titi awọn ẹnu ibode orilẹede Naijiria gbogbo pa ti ko si ni si iwọle-wọde ẹru kankan nibẹ.
Aarẹ Buhari, Ọga agba ileeṣẹ aṣọbode lorilẹede Naijiria pẹlu minisita fun iṣuna ati gomina banki apapọ orilẹede Naijiria, gbogbo wọn ni wọn jade sita lati sọ idi ti wọn fi gbe igbesẹ yii eleyi ti wọn ni o wa lati ori ọrọ abo, ṣiṣe koriya fun awọn agbẹ titi to fi kan idagbasoke awọn ileeṣẹ abẹẹle.
Amọṣa o, lara awọn ohun to mu inira ba araalu nipasẹ igbesẹ yii ni aisi anfani fun awọn eeyan lati jẹ irẹsi eyi to ti di ounjẹ tẹrutọmọ lorilẹede Naijiria n jẹ.
Pataki ounjẹ irẹsi yii lo mu ki inira o de ba araalu nigba ti ko si aaye lati gbe ounjẹ yii wọle.
Eyii lo mu ki owo ori irẹsi o gbowo lori. Apo irẹsi kan ti wọn n ta tẹlẹ ni ẹgbẹrun marundinlogun si mejidinlogun naira lo ti di ẹgbẹrun marundinlọgbọn si ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira.
Lara awọn ọna ti awọn oniṣowo fayawọ n lo bayii lati fi ko iresi wọle ko yee pa ni lẹrin.
Apo irẹsi labẹ ireke

Oríṣun àwòrán, The nation
Ni ọjọ kẹrinla oṣu kọkanla ọdun 2019 ni awọn aṣọbode ni ipinlẹ Niger ati Kogi dena de ọkọ akẹru kan to kun fun apo irẹsi to din mẹjọ ni ọọdunrun eyi ti wọn ko si abẹ spọlọpọ igi ereke. Alukoro ajs aṣọbode nibẹ ni owo iresi naa to miliọnu marun naira.
Bakan naa lo ni awọn onifayawọ miran kan naa ko si gbaga awọn aṣọbode nigba ti wọn ko irẹsi ti owo ori rẹ le ni miliọnu marundinlọgbọn nairasi inu aṣọ tokunbọ ki awọn aṣọbode ma baa mu wọn.
Irẹsi ninu pata ati kọmu?
Ko tan sibẹ, ni aipẹ yii naa ni awọn aṣọbode kan mu arabinrin kan ti o ko irẹsi si inu awọn awọtẹlẹ rẹ bii pata, kọmu ati abẹ aṣọ.

Oríṣun àwòrán, others
Fidio obinrin ọhun tan kari ayelujara ki a to tun ri awọn kan ti wọn ko irẹsi sinu jala epo ti wọn gbe sinu posi.
Iye igba ti irufẹ awọn iwa yii yoo fi tẹ siwaju ko tii ye ẹnikẹni ṣugbọn ohun kan to daju naa ni pe bi ijsba ko ba ṣi ẹnu ibode, ko lee dẹkun. Bi iroyin to si n ti ọdọ ijsba wa ba ṣe e tẹle, ṣiṣi ẹnu ibode yii ko sun mọ rara.
Epo bẹntírò nínú pósí? Àjọ aṣọ́bodè ri jẹ́ríkaanù epo 23

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹ̀ka to ń mójú to jíjí epo rọ̀ọ̀bì láàrin àjọ àṣọ́bode Nàìjíríà ti gba jẹrikà ẹpo bẹtiróò mẹ́tàlelógun ti wọ́n ri ninú pósí ní ẹnu ibodè Naijiria ti idiroko ní ìpínlẹ̀ Ogun.
Agbẹnusọ ajọ asọbode, Abdullahi Maiwada sàlàyé pé àwọn rí pósi ti wọ́n ko epo bẹtiro si ti wọ́n si fi kalẹ̀ sínu ọkọ ayọkẹ́lẹ́ Mazda 626 kan pẹ̀lú nọmba LSD 617 CW.
Ẹnu ibode ìdiroko jẹ́ ọkan lára èyí ti ijọba àpapọ̀ tì pa láti mú ẹ̀dínkù ba bi àwọn ènìyàn ṣe ń ko ẹrù aitọ wọlú.
Láìpẹ́ yìí ni ajọ asọbode ni ki wọ́n ma gbé epo bẹntiro wọ ìwọ̀n kìlómita ogun si ẹnu ibode Naijiria kankan mọ.
Lásìkò tí ààrẹ Buhari ń sọ̀rọ̀ lóri iṣẹ̀lẹ̀ náà, O sàlàyé pé, epo ti Naijiria n lò lábẹ̀le ti din ni ìdá ọgbọ̀n láti ìgbà ti ìjọba òun ti pinu láti ti ẹnu ibode Naijiria gbogbo.













