Buhari ṣè ìfilọ́lẹ̀ ọkọ̀ ìjagun ológun tiwantiwa ní Kaduna

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/@BashirAhmaad

Àkọlé àwòrán, Buhari ṣèfilọ́lẹ̀ ọkọ̀ ìjagun ológun tiwantiwa ní Kaduna
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe ifilọlẹ ọkọ ijagun tiwantiwa lati le sọ agbara awn ọmọ ogun Naijiria di ọtun,

Ni ilu Kaduna lariwa orile-ede nibi ayẹyẹ apero ọlọdọọdun ọga ileeṣẹ ologun Naijiria ni ifilọlẹ yi ti waye lọjọ iṣẹgun.

Ọkọ naa ti o le tẹ ado oloro mọlẹ loju ogun ni wọn pe orukọ rẹ ni Ezugwu MRAP.

Aarẹ Buhari kan saara si awọn ọmọ ogun Naijiria fakitiyan wọn nipa kikoju awọn agbesunmọmi ati didaabo bo orile-ede Naijiria

Ọkọ ijagun ologun tiwantiwa ti aarẹ Buhari ṣe ifilọlẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, Twitter/@BashirAhmad

Aarẹ ṣeleri atilẹyin ijọba rẹ fun ileeṣẹ ologun ki wọn baa le ri awọn erongba wọn muṣẹ.

O tun ni alaafia mọlẹbi wọn ṣe pataki si ijọba.

Aarẹ ni: ''Mo ṣakiyesi ajọṣepọ laarin ẹka imọ ẹrọ ileeṣẹ to ṣe ọkọ yi pẹlu awọn ileeṣẹ tiwantiwa lati gbe iṣẹ ọwọ larugẹ ati idagbasoke ileeṣẹ ologun wa''

O tun sọ pe inu oun dun pe ''akitiyan tawọn ologun Naijiria n ṣe ti bẹrẹ si ni yọri si rere pẹlu ọkọ ti wọn ṣe yi''

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ẹwẹ aarẹ Buhari tun kan saara sawọn ọmọ ogun Naijiria fun ifarajin wọn forile-ede Naijiria.