South Africa: Ọlọ́pàá South Africa rí ẹ̀wọ̀n ọgbọ̀n ọdún he torí ikú ọmọ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, @others
Austin Reynold ni agbofinro ọmọ orilẹ-ede South Africa to ṣẹṣẹ ri ẹwọn re bayii nitori pe wọn ni o ṣe iku pa ọmọ Naijiria kan.
Austin to jẹ kọnsitebulu ọlọpaa jẹ ọmọ ọdun mẹrinlelogun nigba ti o pa ọmọ Naijiria to fi orilẹ-ede South Africa ṣe ibujoko.
Wọn fẹsun kan Austine pe o ṣe iku pa Ebuka Okoli ni agbegbe Durban ni ẹkun Kwa Zulu-Natal ni orilẹ-ede South Africa.
Lẹyin ọjọ mẹta ti wọn ti n ṣe igbẹjọ naa ni ileẹjọ ni o jẹbi yinyin ibọn lu ọmọ Naijiria naa lẹyin ti ọlọpaa naa ja ọmọ Naijiria lole.
Ile ẹjọ ni agbofinro Austine huwa buruku yii lasiko to n ṣayẹwo ohun ini awọn eeyan lọna aitọ ni agbegbe Durban ti Okoli n gbe.
Wọn fi ẹsun ipaniyan kan Austine ati ẹsun ole jija lọna mẹta.
Brinley Pallo to jẹ ẹnikeji Reynold ti wọn jọ huwa buruku yii lo tun jẹri lodi si Reynold nile ẹjọ pe o ṣoju oun.
Adajọ Shyam Gyanda lo da ẹjọ naa lẹyin gbogbo atotonu awọn agbẹjọro.
A maa mu bi iroyin naa ba ṣe n lọ wa fun un yin laipẹ.














