Xenophobia; South Africa ní kí Naijiria se ìwádìí àwọn tó ń gbe òògùn olóró

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹede South-Africa ti ni awọn ọmọ Naijiria to n gbe oogun oloro lo fa isekupani nitori ẹya to n waye ni South Africa.
Minisita fun ọrọ ibasepọ pẹlu awọn orilẹede ni South Africa, Naledi Pandor lo sọ bẹẹ fun awọn akọroyin lorilẹede South Africa.
Pandor wa kesi orilẹede Naijiria lati ran orilẹede South Africa lọwọ lati se iwadii awọn to n gbe oogun oloro wa si orileede won, ki wọn si dena wọn lati ma se wọ orilẹede wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
O fikun wi pe ọpọlọpọ awọn eniyan lo gbagbọ oogun oloro ni ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria to wa ni South Africa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa ni ile-isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko gbe eniyan mẹtalegọrin lori ẹsun pe, wọn kopa ninu ikọlu ti wọn se ni ilẹ isẹ South Africa to wa ni ipinlẹ Eko.
Eyi ni wọn se lati gbẹsan bi awọn orilẹede South Africa se n pa awọn ọmọ orilẹede Naijiria to wa ni South Africa.
- Ọ̀dọ́mọdé Onímọ̀ ẹ̀rọ rèé tó ń ṣe bàálù, ọkọ̀, ilé àti ọkọ̀ ojú omi
- Toyin Abraham rèé, ọmọ ìpínlẹ̀ Edo tó di àràbà nínú tíátà Yorùbá
- Gani Fawehinmi lọ àmọ́ kò kú lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tó dará ilẹ̀
- Kí ni bẹbẹ tí Makinde àti Sanwo-Olu ṣe láàrin ọgọ́rùn-ún ọjọ́?
- Ẹ má jẹ́ kí ayélujára tàn yín jẹ́, mẹ̀kúnnù lọ̀pọ̀ àwa òṣèré tíátà - Iyabo Ojo
Ile ẹjọ sun igbẹjọ wọn di Ọjọ Kẹsan, Osu Kẹwa, ọdun 2019 pẹlu owo itanran ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (N500,000) pẹlu oniduro meji.








