Governors 100 days: Gbadamosi ní àwọn ojú ọ̀nà Eko ń bàjẹ́ si lásìkò Sanwo-Olu

Ayẹyẹ loniranran n waye kaakiri awọn ipinlẹ ti wọn ti burawọle fun awọn gomina wọn ni ọgọrun ọjọ sẹyin, lẹyin idibo gbogboogbo to waye ni ọdun 2019.
Bakan naa ni awọn araalu n se agbeyẹwo isẹ ti awọn ijọba yii ti se laarin osu mẹta ti wọn ti de isejọba ipinlẹ wọn.
Ipinle Eko:

Oríṣun àwòrán, LASG
Ọpọ eto nijọba ipinlẹ Eko ti la kalẹ lati fi se ayẹyẹ ọgọrun ọjọ ti gomina Babajide Sanwo-Olu di gomina.
Lara iru awọn eto bẹẹ si ni sisi akanse isẹ kikọ ilegbe olowo pọọku kan tijọba Eko se agbatẹru rẹ to wa ladugbo Igando., ti gomina naa si tun ya biliọnu mẹrin naira sọtọ bii owoya okoowo alabọde fawọn ọmọbibi ipinlẹ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ko tan sibẹ, ijọba Sanwo-olu tun ti gboogun ti iwa dida idọ̀ti ni aibikita ni Eko to si ti se agbende awọn ajọ kolẹkọdọti ti wọn ti wọgile tẹlẹ pada, to si tun ti ro ajọ̀ LASTMA to n se amojuto eto irinna nipinlẹ́ Eko lagbara si.
Sugbọn lero ti oludije gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu Action Democratic Party (ADP) ni ipinlẹ Eko, Babatunde Gbadamosi, ko si nkan pato ti isejọba ẹgbẹ APC naa ti se laarin ọgọrun ọjọ ti wọn ti bẹrẹ isejọba saa yii.
Babatunde Gbadamosi ni ko si atunse kankan to de ba awọn oju ọna to wa ni ipinlẹ Eko, ati wi pe awọn ti ijọba san owo fun lati se ọna naa dabi ẹni pe wọn ko owo naa jẹ lai se isẹ kankan.
Bakan naa lo ni awọn ọna yii ti ko dara lo n fa sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ ni awọn opopona to wa nipinlẹ Eko.

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu
O fikun wi pe, awọn eniyan ko ri ile gbe, bẹẹ ni wọn n sun si abẹ titi, ati wi pe ipinlẹ Eko tun dọti ju ti tẹlẹ lọ ni saa yii.
Amọ, gbogbo igbiyanju wa lati ba Kọmisọnna fun Eto Iroyin, Gbenga Omotoso sọrọ, ki o le fesi si awọn ọrọ yii lo jasi pabo nitori ko gbe ẹrọ ilewọ rẹ, nigba ti a pe e.
Ipinlẹ Oyo:
Bakan naa ni gomina Seyi Makinde naa ti n pokiki bẹbẹ to ti se laarin ọgọrun ọjọ to ti n tukọ ipinlẹ Ọyọ.
Kọmisana feto iroyin ati asa nipinlẹ Ọyọ, Ọmọwe Wasiu Olatunbosun, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni ijọba Seyi Makinde ti se gudugudu meje, yaaya mẹfa laarin ọgọrun ọjọ to gba ijọba.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Ọlatunbọsun ni Seyi Makinde mu igbelarugẹ ba eto ẹkọ, ilera, owo osu awọn osisẹ, eto ọgbin ati eto aabo.
Ninu ọrọ rẹ, o ni awọn akẹẹkọ ile-iwe alakọbẹrẹ ati girama ko san owo ile iwe mọ ni ipinlẹ Ọyo, ti ẹkọ si ti di ọfẹ gẹgẹ bi Makinde ti seleri lasiko ipolongo ibo rẹ.
- Ìdí rè é tí mo ṣe lọ sí South Africa fún àpérò ọrọ̀ ajé - Ezekwesili ṣàlàyé
- "A ti nílé, dúkìá àti ẹbí ní South Africa, àwa kò ṣetán láti padà sílé"
- Èèmọ̀ rèé o! Tọkọtaya, ọmọ mẹ́ta àti àlejò kú sínú ilé l'Oshodi
- Ìjọba Nàìjíríà ti ránsẹ pé àsoju ijọba ni South Africa láti dari wálé
- Ọlọ́pàá fi afẹ́fẹ́ tajú-tajú àti omi tú àwọn tó fẹ́ ṣun ilé ìtajà ShopRite l‘Abuja ká
Bẹẹ lo ni awọn osisẹ n gba owo osu wọn lasiko, ti awọn ko si fi iya jẹ awọn osisẹ fẹyinti nitori awọn n san owo ajẹmọnu wọn lasiko.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde
Bakan naa lo ni orisirisi alakalẹ lo wa ti awọn ti gbe kalẹ lati mu igbe aye rọrun fun awọn eniyan ipinlẹ Ọyọ ni aarin ọdun mẹrin isejọba Seyi Makinde.
Igbiyanju BBC Yoruba lati gbọ ti ẹnu ẹgbẹ oselu alatako APC nipinlẹ Ọyọ lori isejọba Seyi Makinde laarin ọgọrun ọjọ lo ja si pabo, nitori akọwe ẹgbẹ oselu naa ni ọwọ rẹ di lati ba wa sọrọ.












