Xenophobia: Àwon ọmọ Nàìjíria ni aláìníṣẹ́ nìkan ló leè bá bàálù ọ̀fẹ́ padà wálé

South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Xenophobia: Àwon ọmọ Nàìjíria ni aláìníṣẹ́ nìkan ló leè bá bàálù ọ̀fẹ́ padà wálé

Awọn ọmọ Naijiria kan to n gbe ni orilẹede South Africa ti sọ pe, wọn ko tii ṣetan lati fi ilu naa silẹ lasiko yii.

Ninu ọrọ ti diẹ lara awọn ọmọ Naijiria naa ba BBC Yoruba sọ, awọn ọmọ Naijiria naa ni kiko wa sile kọ lo kan, ipẹtu saawọ ni ọna abayọ si ọrọ ọhun.

Ọgbẹni Fẹmi Ọshin, to jẹ adari eto kan lori afẹfẹ lorilẹ ẹde South Africa sọ wi pe, ko si ninu ipinnu oun lati pada si Naijiria lasiko yii bi o tilẹ jẹ pe ijọba gbe baalu ọfẹ silẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọshin salaye pe oun ni iṣẹ, dukia ati mọlẹbi ni orilẹede South Africa, ti ko si le e rọrun lati kẹru sọkọ lasiko yii.

Awọn ọmọ Naijiria naa wipe, ayafi alainisẹ ati awọn ti iwe igbelu wọn ko pe nikan lo le tẹkọ leti pada si ile.

Ninu alaye yii ni wọn ti fi idi ọrọ mulẹ pe, awọn ti da ile isẹ silẹ ti wọn si ti gbeyawo pẹlu ni South Africa.

Xenophobic attack in South Africa

Oríṣun àwòrán, @cobbo3

Fẹmi tun ni awọn to ba pada sile lasiko yii lee jẹ lara awọn ti o ti nifẹ lati pada sile tẹlẹ, kii ṣe nitori ikọlu to n ṣẹlẹ lakoko yii.

Lero ti Damilola Oluwatuyi, to jẹ oniṣowo ọkọ, oun naa fariga pe oun ko ṣetan lati pada sile.

O ni oun ti n gbe ni orilẹede naa fun ọdun die, ti oun si gbe ọmọ South Africa ni iyawo, bẹẹ ni ko ṣeeṣe lati dede kẹru.

Ni pari ọrọ rẹ, o ni ko si ikọlu ni agbegbe ti oun n gbe ni Johannesburg, nitori naa, oun ko ṣetan lati pada si orilẹede Naijiria.