Ooni: EFCC, ẹ se àtúnse sí ìgbé ayé àwọn ọdaràn tẹ bá mú

Ọọni ti Ile-Ifẹ, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, ti kesi Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC pe ki wọn se atunse lori awọn ọna ti wọn n gba gbogun ti iwa ọdaran lawujọ.
Ọba Ogunwusi ni o seese ki awọn ọdaran yii ma mọ ijamba ti wọn n se fun ara ilu, nitori naa, ti ọwọ ba tẹ awọn afurasi ọdaran wọn yii, ki wọn se ifọrọwanilẹnuwo fun wọn daadaa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìdájọ́ ọmọ mi tó gbé àdó ìkú wọ bàálù le púpọ̀, ẹ bá mi wòó ṣe - Bàbá Mutallab
- Ọ̀dọ́mọdé Onímọ̀ ẹ̀rọ rèé tó ń ṣe bàálù, ọkọ̀, ilé àti ọkọ̀ ojú omi
- Wada la Dino mọ́lẹ̀ nínú ìbò abẹ́lé PDP fún ìpò gómìnà ní Kogi
- Ìjọba Nàìjíríà ti ránsẹ pé àsoju ijọba ni South Africa láti dari wálé
- Èèmọ̀ rèé o! Tọkọtaya, ọmọ mẹ́ta àti àlejò kú sínú ilé l'Oshodi
Ọba Ogunwusi gbe imọran ọhun kalẹ lasiko to n gbalejo awọn osisẹ agba ajọ EFCC ni aafin rẹ nilu Ile Ifẹ.

Bakan naa, ni Ọọni tun ke gbajare lori bi iwa ọdaran se peleke si ni ipinlẹ Ọsun, to si kesi awọn ọdọ lati jawọ ninu iwakiwa, bẹẹ lo tun kesi ajọ naa lati fi agbara kun bi wọn se n gbogun ti iwa ọdaran ni awujọ.
Ninu ọrọ ti wọn, ajọ EFCC naa wa rọ Oba Adeyeye Ogunwusi lati kesi awọn ọba ni ile Yoruba, ki awọn naa tiraka lati gbogun ti iwa ibajẹ ni agbeegbe wọn.








