Child Engineer: Olamide Odukọya ní òun fẹ́ ṣe ohun kan tí yóò wúlò fún gbogbo àgbáyé

Àkọlé fídíò, Child Engineer: Olamide Odukọya nílò ìrànlọ́wọ́ láti lọ síléẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ

Ọmọ ti yoo ba jẹ Aṣamu, kekere ni yoo ti maa jẹnu ṣamu-ṣamu.

Bi ọrọ Olamide Odukọya se ri gẹlẹ ree, ẹni to ti n se awọn baalu kekere lorisirisi, ọkọ oju omi, mọto ati ile lati ọmọ ọdun mejila.

Olamide ni ọpọlọ oun ni oun n lo, ko si si ẹnikẹni to kọ oun nisẹ naa, bi oun ba si ti ri mọto tuntun, abi orisi ọkọ ofurufu tuntun, ni oun yoo se sita.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọdọmọde onimọ ẹrọ naa salaye pe oun maa n fun awọn ọmọde ni awọn isẹ ọwọ oun naa lati fi sere ni, amọ eyi to ba jẹ agbayanu ninu awọn isẹ ẹrọ naa, ni oun maa n fi pamọ.

Olamide wa beere fun iranlọwọ latọdọ ijọba lati lọ kọ ẹkọ ni ile ẹkọ nipa imọ ẹrọ, ki oun lee se ohun nla-nla ti yoo jẹ itẹwọgba fun gbogbo eeyan agbaye ati awọn ijọba ni orilẹede agbaye.