Downsyndrome: Dayo ń wa mótò, ó fẹyawọ, o tún lọ ilú òyìnbó
Baba Dayo ni ǹkan tí òun ti rí nípa ọmọ rẹ̀ tó ni Downsyndrome fi han pé kò sí ọmọ ti ko wúlò .
Usman Yahaya to jẹ́ bàbá Dayo ni bí àwọn ṣe bi Dayo ni iya oun ti gbà ọmọ náà láti tójú, ṣùgbọ́n àsìkò to bẹ̀rẹ̀ si ni lọ ilé ẹkọ, òun ṣe àkíyesi pé kò dẹrùn fun láti kọ iwé.
Baba Dayo ni, lẹ́yìn èyí ni oun ṣe akiyesi ǹkan ti o fẹ́ràn láti maa ṣe, eyi ti òun fi mu lọ si ilé awọn to n gẹrun
"Dayo fẹ́ràn láti maa wakọ, ó fẹ́ràn aṣọ lílọ, o si le ṣe gbogbo ǹkan ti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ le ṣe.'"
Alhaji Usman rọ gbogbo òbi ti o ni irú ọmọ bẹ́ẹ̀ láti wádìí ǹkan ti wọ́n fẹ́ràn nítori ó ṣe pàtàkì láti fi ọjọ iwáju wọ́n léwọn lọ́wọ́