Budget 2020: Ilé aṣòfin àgbà buwọ́lu àbá ìṣúná N10.59trn fún ọdún 2020

Gbagede gngan ile aṣofin agba

Oríṣun àwòrán, nigeria Senate

Ile aṣofin agba ti buwọlu abadofin iṣuna orilẹede Naijiria fun ọdun 2020.

Iṣuna oni tiriliọnu mẹwa abọ o le diẹ naira, N10.59trn ni wọn buwọlu lẹyin o rẹyin.

Aba oni triliọnu mẹwa o le ọdunrun biliọnu naira ni aarẹ gbe ka iwaju ile naa ni sjọ kẹjs oṣu kẹwaa ọdun 2019.

Amọṣa lẹyin ijoko ati ifikunluku awọn igbimọ tẹẹkoto gbogbo ni ile aṣofin mejeeji, awọn aṣofin agba fi ọtalelugba o le mẹta bilisnu naira kun un.

Lara afikun yii, awọn aṣofin apapọ fi biliọnu mẹta kun bilisnu marunlelọgọfa bilisnu naira ti wọn ya sọtọ fun wọn tẹlẹ.

Ninu ọrs to sọ lori afikun naa, alaga igbims lori iṣuna ni ile aṣofin agba, Muktar Batera ni afikun ọhun waye lati mojuto awọn eto to nii ṣe pẹlu idagbasoke ilu.

Nigba to n gbe abajade rẹ sita, Sẹnetọ Jibrin barau ṣalaye pe afikun aadọrun bilisnu Naira waye fun amojuto ipenija abo lorilẹede yii, eto fawọn aṣofin ati iranwọ fun ipinlẹ Zamfara.