EKSU: Fásitì EKSU lé òṣìṣẹ́ tó lé ní 600 lórí ẹ̀sùn ìwé ẹ̀rí, ọjọ́ orí

Iloro fasiti Ekiti

Oríṣun àwòrán, Vanguard news

Fasiti ipinlẹ Ekiti, EKSU ti le ẹẹdẹgbẹrun oṣiṣẹ rẹ niṣẹ.

Giwa fasiti naa, Ọjọgbọn Eddy ỌỌlanipẹkun ṣalaye pe abajade iwadi ileeṣẹ atọpinpin iṣuna kan lori iṣuna ati oṣiṣẹ ileeṣẹ naa lo mu eyi wa.

O fi kun pe wọn gbe igbesẹ naa lori aba ti igbimọ olubẹwo ti gomina ipinlẹ naa, Kayọde Fayẹmi gbe kalẹ, eyi to tọka si apọju oṣiṣẹ ni gbogbo ẹka fasiti naa gẹgẹ bi ipenija kan ti ileeṣẹ naa ndojukọ.

Iroyin sọ pe, awọn oṣiṣẹ ti wọn gba siṣẹ laarin ọdun 2016 si 2018 lọbẹ igbesẹ naa ba nidi julọ atipe igbasiṣẹ wọn ti mu iye owo sti fasiti naa n na o tubs pọ si ni ilọpo ọgọrun laarin ọdun mwji.

Gẹgẹ bi ọrọ giwa fasiti naa, o le ni igba awọn oṣiṣẹ fasiti naa ti ko lee fi iwe ẹri ileewe alakọbẹẹrẹ wọn han. Bẹẹni aimọye orukọ ni wọn ri to n gba owo oṣu ṣugbọn ti orukọ wọn ko si ninu iwe oṣiṣẹ fasiti naa.

Bakan naa ni giwa fasiti naa tun ṣalaye pe ọpọ ninun wọn ni ọjọ ori wọn ti kọja ọdun ti ofin la kalẹ fun ati ṣiṣẹ ni fasiti.