Disability in Africa: 'Ojú kò tì mí mọ́ pé ọmọ mi ní ìpènéjà ara'

Nígbà tí Agnes Mutemi kọ́kọ́ gbọ́ pé àkọ́bí rẹ̀ obìnrin, Nambia, ní ààrùn ọpọlọ l'ọ́mọ ọdún méjì, ìtìjú nla ló jẹ́ fun un.
Bẹ̀ ẹ́ ni kò sì fẹ́ ẹ̀ gbàgbọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, kó tó ò di pé ó ṣàwárí iléèwé kan tó n tọ́jú àwọn ọmọdé tó ní ìpèníjà ara.
Ìyá ọlọ́mọ mẹ́ta ọ̀hún sọ pé ìbànújẹ́ òun maa n wáyé látara bí àwọn ènìyàn ṣe maa n wo òun, àti ìhùwàsí wọn si i lójoojúmọ́.
"Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, mó maa n bi ara mi lérè pé kí lódé tí Ọlọrun fún mi nírú ọmọ bẹ́ẹ̀.''
Abílékọ Mutemi, tó n gbé l'ábúlé Katoloni ní ẹkùn ìlà oorùn Kenya sọ pé ''Ó ṣòro fún mi láti rìn láàrin ìlú pẹ̀lú ọmọ mi, nítorí ojú burúkú tí àwọn ènìyàn fí n wò mí.
Agnes sọ pé àìsàn tí wọ́n n pè ní Asphyxia ni ọmọ òun ní. Àìsàn nàá maa n jẹyọ tí ọmọ tuntun kò bá rí atẹ́gùn gbà sára lásìkò tí ìyá rẹ̀ bá n rọbí.
Èyí ló fà á tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò ṣe ní àláàfíà, tí wàhálà sí bá ọpọlọ rẹ̀ nàá.
Bí o ṣe gba ìwòsàn
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àbẹ̀wò sí iléèwòsàn, Agnes lọ fi orúkọ ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ ní ìléèwé kan tó n kọ́ àwọn ọmọdé nígbà tó wà l'ọ́mọ ọdún mẹ́ta.
''Ìgbà tí Nambia lo ọdún mẹ́fà ní kíláàsì kan, tí kò sí le ṣe àwọn nkankan tó jẹ́ dandan, ni mo tó ò mọ̀ pé nkan kò lọ déèdé.
Ó fi kun un pé owó ìtọ́jú ẹni tó bá ní ààrùn ọpọlọ ti pọ̀jù ní Kenya.
''Ohun tó wù mí ni pé kí ọmọ mi di dókítà tàbí ọ̀jọ̀gbọ́n, tàbí olùkọ́. Ṣùgbọ́n, ó ṣe ni láànú pé èyí kò ní ṣeeṣe.

Ní ìkóríta kan, Agnes tilẹ̀ pinnu láti maa jókòó sílé pẹ̀lú Nambia, nítorí pé àwọn iléèwé tó wà fú àwọn ọmọ tó dápé kò gbà á.
Ṣùgbọ́n, ohun tó mú àyípadà bá ayé Agnes ni àsìkò tó pàdé ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtijọ́ kan, tó gbà á nímọ̀ràn pé kó mú ọmọ rẹ̀ lọ sí àkànṣe íléèwé.
"Lẹ́yìn tí miò rí àyípadà lára ọmọ mi ní mo tó gba kádàrá.
"Mi o tan ara mi mọ́.''
Lóòtọ́ ni Nambia ní ìpèníjà ara, ṣùgbọ́n èyí kò di i lọ́wọ́ láti má gbé ìgbé ayé rẹ̀ pẹ̀lú ìdùnnú.
Nambia jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ènìyàn tó lé ní bílíọ́nù kan tó n gbá pẹ̀lú ìpèníjà ara l'ágbàyé.

Oríṣun àwòrán, AFP
Àjọ tó n mójútó ètò ìlera l'ágbàyé, WHO sọ pé ìdá mẹ́ẹ̀dógún àwọn ènìyàn tó wà l'áyé ni yóò ní ìpèníjà ara kan, pàápà ní àwọn orílẹ̀èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ n dàgbà.
Gẹ́gẹ́ bi àkọsílẹ̀ àjọ Unesco, ìdá àádọ́rùn nínú àwọn ọmọ tó ní ìpèníjà ara l'áwọn orílẹ̀èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ n gòkè, ni kìí lọ sí iléèwé.
Ní Kenya, ibùdó ẹgbẹ̀rún kan lé ọ̀ọ́dúnrún ni wọ́n ti n tọ́jú àwọn tó ní ìpèníjà ara, àti iléèwé ọgọ́fà dín mẹ́fà, gẹ́gẹ́ bi àkọsílẹ̀ ilé iṣẹ́ tó n mójútó ètò ẹ̀kọ́ l'ọ́dún 2009.
Ṣùgbọ́n, kò tó, kìí sì ṣe gbogbo ọmọ tó ní ìpèníjà ara ló n rí ìtọ́jú bi Nambia.
Àbọ̀ ìwádì ọ̀hún fihàn pé ìdá àádọ́rùn nínú àwọn ọmọ tó ní ìpèníjà ara ní Kenya, ló n jókò sílé tàbí lọ sí iléèwé tí kìí ṣe fún àwọn tó ní ìpèníjà ara, tí wọn kìí sì rí ìtọ́jú tó péye gbà níbẹ̀.
'Ọmọ mi ni ohun gbogbo fún mi'
Ìgbá ayé kò rọrùn fún àwọn òbí tó ní ìpèníjà ara, tó sì tún n pèsè fún àwọn ọmọ wọn.

Irene Kerubo, ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n, gbẹ́kẹ́lé ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá, láti tìí pẹ̀lú kẹ̀ẹ̀kẹ́ lọ sí ilé ìtajà rẹ̀ ní òwúrọ̀ ojoojúmọ́ kó tó lọ sí iléèwé ní agbègbè Nakuru ní Kenya.
Èyí ni bí Kevin Momanyi ṣe n lo ayé rẹ̀, nítorí pé ìyá rẹ̀ ní àárùn rọmọlápá, rọmọlẹ́sẹ̀ nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mẹ́rin, èyí tó mú kó yarọ láti ìbàdí dé ẹsẹ̀ rẹ̀.

"Ọmọ mi, ọmọ ọdún mẹ́wàá ni ohun gbogbo fún mi."
Ìyá ọlọ́mọ mẹ́rin ọ̀hún sọ pé ''òun ló n ṣe gbogbo iṣẹ́ ilé, tó sì tún n pèsè oúnjẹ́ fún wa nítorí pé óun tì mí pẹ̀lú kẹ̀ẹ̀kẹ́ lọ sí ilé ìtajà mi.''
Ipò tó wà ti jẹ́ kó wà nínú ìṣẹ́ àti òṣì.















