YSAN 2018: Ìgbélárugẹ èdè Yorùbá wúlò fún gbogbo ọmọ Yorùbá
Ọjọgbọn Onimọ Ede Yoruba ti sọ wi pe iran to bá gbagbe èdè rẹ, tabi ti won ba gba a lọ́wọ́ rè, tí ṣègbé.
Aarẹ Ẹgbẹ Onimọ Ede Yoruba, Ọjọgbọn Durotoye Adeleke lo sọ eyi nibi ipade igbelarugẹ ede Yoruba to waye ni ilu Ondo ni ọgba Ile-Iwe Giga Adeyemi College of Education.
Ọjọgbọn Durotoye ke si gbogbo ipinlẹ kaarọ ojiirẹ lati kọ ẹkọ lara ipinlẹ Eko to gbe ede Yoruba larugẹ nibi gbogbo ati nibi itaja pẹlu.
Ilé iṣẹ́ BBC Yorùbá gbe Ede Yoruba larugẹ
ile ise iroyin bbc yoruba náà balẹ̀ bìbà síbi ètò ìpàdé àpérò náà láti sọ bí ilé iṣẹ́ ìròyìn BBC lápapọ̀ ṣe ní ìjẹlọ́kàn fún èdè Yorùbá.
Olootu iléese BBC ni ẹkùn ìwọ oòrùn Áfíríkà, Oluwatoyosi Ogunseye tí ni àfojúsùn àgbékalè BBC Yoruba ni láti ṣe agbega àṣà àti èdè Yorùbá.
Ogunseye ni BBC ń fẹ́ ifowosowopo àwọn onímò nípa ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá láti mú kí èdè Yorùbá gòkè àgbà.

Ó wà béèrè fún àwọn onímò èdè Yorùbá tó jẹ́ ónkọ̀wé láti yonda àwọn ìwé wọn fún BBC Yoruba, ká leè máa ka fáwọn ọmọ Yorùbá lórí ètò Àyọkà.
Ó tún ro àwọn lọba lọba, ọtọkulu ìlú, àtàwọn olólùfẹ́ èdè Yorùbá lagbaye, láti maa ka BBC Yoruba lójú òpó ayélujára.
Ogunseye tún fi dá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ YSAN lójú pé BBC Yoruba yóò ṣètò ìdíje nínú èdè àti àṣà Yoruba láàárín àwọn ọdọ pàápàá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga káàkiri orílẹ̀ èdè Naijiria.
Lákòótán, Ogunseye wá gbàdúrà fún ysan pé akalamagbo won kò ní pa ọdún jẹ, iwájú ni ọ̀pá ebiti ẹgbẹ́ náà yóò máa re sì.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ ojogbon Dúró Adeleke, tíí ṣe Ààrẹ ẹgbẹ́ YSAN

Ọ̀jọ̀gbọ́n Duro Adeleke tó jẹ́ ààrẹ ẹgbẹ́ àpapọ̀ àwọn onímọ̀ èdè Yorùbá tẹnu mọ́ ipa pàtàkì ti èdè Yorùba ń kó.
Ó mẹ́nu bà á pé gbogbo àwọ́n ilé ìwé, ilé iṣẹ́ ìròyìn àtí ọlọ́dani tó bá wá síbi ètò náà ni yóò rí ẹ̀kọ́ kọ́ nípa àmúlò èdè Yorùbá fún iṣẹ́ oníkálùkù wọn.
Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn onímò nípa èdè Yorùbá, YSAN, ọjọgbọn Dúró Adeleke tí ni àkòrí ìpàdé àpapọ̀ ẹgbẹ́ YSAN fún ọdún yìí, tíì ṣe "èdè nínú imọ, imọ nínú èdè" ṣe rẹ́gí pẹ̀lú àfojúsùn àjọ unesco fodun 2030.

Adeleke ni èdè abínibí wá wúlò fún ìmò, òye àti ọgbọ́n láàrin gbogbo ẹ̀dá.
Ó ṣàlàyé pé ẹni tí kò bá ronú jinle ni yóò fi ọwọ yẹpẹrẹ mú èdè abínibí rẹ, tó sì rọ àwọn ọmọ Yorùbá láti máa ṣe igbega àṣà Yoruba.
Níparí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Adeleke ni ó yẹ kí ìran Yorùbá máa rántí asamo àjọ UNESCO tó ní iran tí wọn bá gba èdè rẹ lọ́wọ́ rè, tí ṣègbé.

Ìgbáradì fún ìpàdé Ẹgbẹ́ Onímọ̀ Yorùbá

Ìgbáradì fún ètò
Igbaradi bẹ̀rẹ̀ fún ìpàdé àpérò ọlọdọọdun Ẹgbẹ́ Àpapọ̀ Àwọn Onímọ̀ Èdè Yorùbá (Yoruba Studies Association of Nigeria ) YSAN 2018 ní Ìpínlẹ̀ Ondo.
Ninu ọgba ile ẹkọ Adeyemi College of Education, nilu Ondo l'eto naa ti n waye.
BBC Yorùbá náà sì ti wà níkàlẹ̀ láti gbé àṣà Yorùbá lárugẹ níbi ètò ọ̀hún.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Koda awọn oluranlọwọ eto fun alejo gan ko gbẹyin bi wọn ti wọ aṣọ ibilẹ lati gbe aṣa Yoruba larugẹ.

Opeyemi Bioke jẹ ọkan lara awon oluranlọwọ alejo níbi ètò naa, bi o ti we gele aṣọ oke lo mu irukẹrẹ dani.
Awọn ọmọ ile iwe girama ko gbẹyin nibi eto yii lati kọ nipa amulo ede Yoruba latẹnu awọn agbaagba atawọn ọjọgbọn Yoruba.

















