Sowore: Iléeṣẹ́ DSS tú Sowore sílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ 125 ní àhámọ́

Ọmoyele Sowore atawọn eeyan rẹ

Oríṣun àwòrán, Sahara reporters

Ileeṣẹ agbofinro ọtẹlẹmuyẹ DSS ti tu ajafẹtọ ni, Ọmọyẹle Sowore silẹ.

Awọn oṣiṣẹ DSS gbe Soworẹ lasiko tio fi n lewaju iwọde #Revolution now.

Itusilẹ rẹ n waye lẹyin ti o ti lo ọjọ marundilaadoje ni ahamọ awọn DSS.

Oniruuru idajọ lo ti waye eyi ti awọn ile ẹjs lorilẹede Naijiria ti ni ki wọn fi silẹ ṣugbọn ti awọn alaṣẹ ileeṣẹ DSS kọ jalẹ pẹlu oniruuru awawi.

Sowore, Amofin Falana, bakare atan eeyan kan

Oríṣun àwòrán, Sahara reporters

Amọṣa ni ọjọbọ ni ileẹjọ miran tun pa aṣẹ ki ileeṣẹ Ọtẹlẹmuyẹ DSS o tu u silẹ laarin wakati mẹrinlelogun.

Ireti wa pe yoo tun farahan ni ile ẹjọ ni ọjọ Ẹti ni itẹsiwaju igbẹjọ rẹ.

Ni ọjọ kẹta oṣu kẹjs ọdun 2019 ni awọn agbofinro DSS lọ gbe Ọmọyẹle Soworẹ lori ẹsun pe o n ṣe agbatẹru awọn iwọde #revolutionnow eleyi to n beere fun iṣejọba rere lorilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, FUTA: Àwọn mẹ́jọ ló ṣíná ìyà fún Bolu ní FUTA

Ni ajọ kẹfa oṣu kọkanla ni ọgbẹni Soworẹ kọkọ mu ileri beeli akọkọ ti ile ẹjọ fun ṣẹ ṣugbọn ti ileeṣẹ DSS ko tuu silẹ.

Ọru ifisahamọ Sowore ti mu ọpọlọpọ awọn ajọ ilẹ okeere ati ti Naijiria pẹlu lati kigbe si ijọba apaọ lati bọwọ fun ofin ṣugbọn ti ileeṣẹ DSS kuna lati tu u silẹ gẹgẹ bi awọn aṣẹ iṣaaju lati ile ẹjọ.

Bakan naa ni ileeṣẹ DSS tun da Olawale Bakare naa silẹ.

Awọn mejeeji yi ni ijọba apapọ n fi ẹsun iditẹ gbajọba kan.