Oluwo Divorce: ko si ẹni ti kò mọ pé ọmọ ilẹ̀ òkèrè ni mó fi ṣe aya
Nínú oṣù keje, ọdún yìí ni Oluwòó sọ̀rọ̀ nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan pẹ̀lú BBC.
Kabiesi ṣalaye pé ọmọbinrin to rẹwa ní aya ti òun fẹ́ síle, eyi jẹyọ lásìkò ti BBC bèrè ọ̀rọ̀ lóri ẹ̀sùn ti Alfa kan ni ìlú Iwó fi kan an.
Ninu fọ́nran kan to fi ìgbà kan jà rànyin-ranyin lóri ayelujára nibi ti Kabiyesi Abdulrashed Akanbi ati Aafa náà ti n ni àriyanjiyan lori pé Kabiyesi n fẹ aya Aafa Iwo.
Sùgbọ́n lọ́jọ́ Aiku ọ̀ṣẹ̀ yìí ìyàlẹ́nu lọ́ jẹ nígbà ti Ọba Akanbi fi lédé lórí àtẹjisẹ́ instagram rẹ̀ pe Oun ti fi ìyàwo oun sílẹ̀.
Iṣẹ̀dá fọ́nrán láti ọ́wọ́ Damilọ́la Oduolowu àti Yemisi Oyedepo