Sex for Grade: Òkété bórù mọ àwọn ọjọgbọ́n méji lọ́wọ́, UNIABUJA jù wọ́n síta

Fasiti Abuja
Àkọlé àwòrán, Sex for Grade: Òkété boru mọ àwọn ọjọgbọ́n méji lọ́wọ́ UNIABUJA jùwọ́n síta

Fásíti Abuja ní àwọ́n ti fọ́wọ́ osì júwe ilé fún àwọn ọjọgbọ́n méji kan ni ní ọgbà ilé iwé wọ́n fún ìwà fẹ̀yìn lélẹ̀ tàbi sànwo kí o gba máàkì

Fasiti náà nínú àtẹjáde rẹ̀ fidi rẹ̀ múlẹ̀ pé Ọ̀jọ̀gbọ́n Adeniji Adedayo tó jẹ́ olórí ẹ̀ka ẹkọ́ ètò ọ̀gbìn àti Chibuzo Orji ní ìgbá ọ̀rọ̀ náà ṣímọ lóri.

Wọ́n ní Adedayo ń hu ìwà àìtọ́ pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ obinrin ni fásìtì náà nígbà ti Orji to jẹ́ olùkọ́ ẹka sáyẹnsi àti ètò àyíká ń yí ìwé ìdánwò àti lílọ́wọ́ nínú màgàmágó nínú ìdánwò.

Atẹjáde náà ti olori ẹka ọ̀rọ̀ to n lọ fun Fasiti Abuja, Onimọ Habibi Yakoob fọ́wọ́ si ni Fasiti náà ti kọ̀wé lọ́ rọ́ọkún nilé fún wọ́n gẹ́gẹ́ bi ibi ti ìgbìmọ̀ aláṣẹ fásiti náà fẹnuko si lẹ́yin ìpàdé wọ́n lọ́sẹ̀ tókojá.

Atẹjáde náà ní "Awọn ọjọgbọ́n méji, Chibuzo Orji ati Adedayo ti ẹka ẹkọ sayẹnsi àti ètò àyíka ni ọrọ kan.

Fasiti Abuja paṣẹ yii fun lilọwọ si yiyi iwe ìdánwò àti ríràn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti jiwe wò eyi ti ko si ba ofin ilé ẹkọ náà mu"

Igbìmọ̀ náà tún buwọlu jíjá iràwọ ọmọwé Robert Dajal wálẹ̀ ní ẹka ẹkọ sayẹnsi àti ètò àyika láti ipo to sún mọ olùbákẹ́gbẹ́pọ̀ àwọn ọjọgbọ́n si olùkọ àgbà.

Bakan na ni iwadii tun kan ọgbẹni Gana Defian ti ẹka ẹkọ imọ ogbin àti ẹranko láti ipo olùkọ kinni sí olùrànlọ́wọ́ olùkọ fún àwọn ìwà ibàjẹ́ to ta àbuku ba fasiti Abuja"

Àkọlé fídíò, Iná PHCN tó dé lójijì ṣàkóbá ńlá ní Ibadan

Agbẹnusọ ilé ẹkọ náà, Hajiya Maryam Mohammed sàlàyé pé olori ẹka ẹkọ tẹ́lẹ̀, ọjọgbọ́n Adeniji ni wọn ti ni ko lọ rọọkún nile tẹ́lẹ̀ nítori ẹsun pé o n fi ìbálópọ̀ dúnkooko mọ akẹ́kọ́ọ̀.

Ile ẹkọ́ gbe igbimọ iwádìí díde wọ́n si ti ni ko lọ rọọkún nilé.

Iroyin ni wọ́n fa ọjọgbọ́n náà le ọlọpàá lọ́wọ́ ninú oṣù kẹrin, lẹ́yin ti àwọn akẹ́kọ́ọ̀ tan an lati ṣe ipade ni ilé itura kan ni Gwarimpa ni Abuja.

Lọtẹ yii, ọ̀rọ̀ náà sẹlẹ̀ lásìkò ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń se idaanwo sáà kini 2018/2019.

Àwọn akẹ́kọ́ọ̀ náà lọ fẹ́jọ sun àwọn ẹ̀ṣọ́ ilé iwé náà ti wọ́n sì sọ fún wọ́n pé ki wọ́n tẹ̀si ibi ti olukọ náà tẹsi sùgbọ́n ki wọ́n fi to ọlọpàá léti, bẹ́ẹ̀ ni àṣírí ọ̀rọ̀ ṣe tú"