Ibadan Fire: Ẹ wo bí iná ṣe ṣọṣẹ́ tí àwọn oníṣòwò sì pàdánù ọ̀pọ̀ mílíọ́nù náírà nílú Ibadan

Awọn oniṣowo ti padanu ọja ati irinṣẹ to le ni ogunlọgọ miliọnu naira nilu Ibadan ni ipinlẹ Oyo ni guusu Naijiria lataari ina kan to deede ṣẹyọ lalẹ ana.

Iṣẹlẹ ina ọhun lo waye lagbegbe ile iwosan Oni and Sons Memorial, to wa ni Bashorun MKO Abiola Way, ni Ring Road.

Agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti ṣe jẹ eyi ti awọn ileeṣẹ to n pese ohun eelo bi ọra loriṣiriṣi ati ike kalẹ si.


Awọn oṣoju mi koro sọ pe, ina ọhun bẹrẹ ni igba ti awọn oṣiṣẹ awọn ileeṣẹ naa ti palẹ mọ tan.

Wọn ni ina naa ṣẹyọ lati ara opo ina mọnamọna, lẹyin ti ajọ amunawa tan ina si adugbo ọhun.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe ẹnikan lo kọkọ ri ina ọhun ko too ke pe awọn eeyan adugbo lati paa, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.
Awọn ileeṣẹ naa ti wa lagbegbe Ringroad fun nkan bi ọdun mẹrindinlogun, ti wọn si n pin ọja wọn kaakiri orilẹ-ede Naijiria.

Ni ṣe ni awọn ti ọrọ naa kan n domi loju, awọn mii tilẹ dero ile iwosan ni kete ti wọn gbọ iroyin ọhun.

Ọkan lara awọn ti ọrọ naa kan sọ fun BBC pe, lara awọn ti ṣọọbu wọn jona jẹ akẹkọjade to ṣẹṣẹ kawe tan ti wọn si n taraka lati wa ọna atijẹ ni.
Iroyin ni awọn ileeṣẹ to ba iṣẹlẹ ọhun lọ to marundinlogun.

Bẹẹ naa ni awọn irinṣe ti iye rẹ to ọgọta miliọnu ati awọn eroja ti wọn fi n ṣe ọra, ike ati awọn ohun mii lo ba ina ọhun lọ.













