Fani-kayode: Kàkà kí n darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, màá yáa fikú ṣèfàjẹ

Oríṣun àwòrán, facebook/Femi Fani-Kayode
Minisita tẹlẹ fun eto irinajo ọkọ ofurufu, Femi Fani-kayode ti sọ pe oun yan lati ku, ju ki oun darapọ mọ ẹgbẹ APC lọ.
Fani-Kayode lo sọ ọrọ naa loju opo Twitter rẹ latari iroyin kan to ni o ti darapọ mọ ọhun.
O ni "Mo ti pinnu lati maa ṣe atako ẹgbẹ oṣelu APC titi di ọjọ iku mi, ko si ohun kohun to lee mu mi darapọ wọn."
- 'IBB tẹ ń pariwo pé ó kú, kò kú o, Ko ko ko lara ọta ń le! - Agbẹnusọ Kassim
- China o, Nàìjíríà o, kò s'áyè òwò mọ́ ní Ghana! - Ààrẹ Akufo-Addo
- Ọ̀jọ̀gbọ́n fásitì OAU pàdánù ẹ̀mí lópoópónà Benin sí Auchi.
- 'À ń gbé àkàsọ̀ bọ̀ wá já iná yín ní Togo, Benin bí ẹ kò bá sanwó'
- Kamaru Usman, Ọmọ Naijiria f'ẹ̀ṣẹ́ gba ìgbànú ẹ̀yẹ mọ́ Covington lọ́wọ́ ní ìdíje UFC
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Minisita ana ọhun tẹsiwaju pe, okunkun ni ẹgbẹ APC jẹ, ti oun si jẹ ọmọ imọlẹ, ati pe ko si ibaṣepọ kankan laarin okunkun ati imọlẹ.
O ni ololufẹ maalu ni APC, ati pe awọn oniwa ibajẹ ati jẹgudujẹra ti ko ni aba rere kankan fun orilẹ-ede yii lo kun inu ẹgbẹ ọhun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Fani-Kayode ni irọ pata ni iroyin ti awọn kan n gbe kiri pe oun darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu naa.