Miss World 2019: Toni-Ann Singh gbadé gẹ́gẹ́ bi omidan tó rẹwà jùlọ lágbáyé

Tini-Ann Singh

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, omidan tó rẹwà jùlọ lágbáyé lọ́dun 2019

Toni-Ann Singh lati lorilẹ-ede Jamaica ti gbade gẹgẹ bi omidan to rẹwa julọ lagbaye fun ọdun 2019.

Ọmọ ọdun mẹtalelogun ọhun lo jawe olubori laarin awọn omidan mẹrinlelaadọfa akẹgbẹ rẹ to kopa ninu idije naa.

Aṣeyọri yii ti mu ki Singh jẹ ẹni kẹrin lati orilẹ-ede Jamaica ti yoo gbade ọhun.

Idije omidan to rẹwa julọ lagbaye ti ọdun 2019 yii ni ikankandinlaadọrin iru rẹ.

Ṣaaju ni omidan ọhun ti sun si ọkan lara awọn ogoji to to pegede julọ ninu idije naa lẹyin to fakọyọ nibi ase to waye ni ilu London.

Lẹyin naa lo sun si ipele to kẹyin ninu idije naa.

Omidan lati ilẹ Faranse lko gbe ipo keji, lẹyin naa ni omidan India ati Brazil.

Nyekachi Douglas lati orilẹ-ede Naijiria lo gbe ipo karun un.

Àkọlé fídíò, Taa gan ló ń jí orin àti ohùn ara wọn lò nínú Adewale Ayuba àti Ajebori